Ọkùnrin kan fún akẹ́kọ̀ọ́ lọ́rùn pá ní Ondo

Oríṣun àwòrán, others
Ilu Arogbo nijọba ibilẹ Ese-odo nipinlẹ Ondo ni igbe ẹkun ti ta lọjọ Aje ọsẹ yi lẹyin ti ọkunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Oke Loya ṣekupa ọdọmọkunrin ọmọ ọdun mẹtadinlogun kan, Timibra Meretighan, ninu ile ẹkọ rẹ.
Iroyin to tẹ BBC News Yoruba lọwọ lati ilu naa ni pe Timibra ati awọn akẹgbẹ rẹ ni wọn n kọ idanwo ninu kilaasi ni ile ẹkọ Ijaw National High School ni Arogbo lọjọ naa ko too di pe Oke wọ kilaasi lati le gbogbo awọn akẹkọọ ọun jade.
Wọn ni lakoko to n le wọn jade lo mu Timibra to si fun-un lọrun pa.
Eyi lo si fa aruwo ati idarudapọ to fẹẹ mi omi alaafia ilu naa diẹ ko too di pe awọn agbofinro fi panpẹ ọba mu ọkunrin naa.
Alukoro ajọ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Funmilayo Odunlami-Omisanya to fi idi ọrọ naa mulẹ ninu ifọrọwerọ pẹlu akọroyin BBC News Yoruba wi pe awọn ti mu ọkunrin naa, wọn si ti bẹrẹ iwadi ni kikun.
Ọdunlami-Omisanya ṣee lalaye pe ọga agba ile ẹkọ naa lo sa lọ agọ ọlọpaa lati fi to awọn agbofinro leti pe “ọkunrin kan, Oke Loya, ọmọ ọdun mẹtadinlọgbọn sa wọ ile ọlọdẹ nile ẹkọ naa kati farapamọ fun ojo amọ to pada gbẹmi akẹkọọ oun kan.
Alukoro ajọ ọlọpaa naa tẹsiwaju pe “Timibra Meretighan, ọmọ ọdun mẹtadinlogun lati Arogbo-Ibe ni ọkunrin naa fun lọrun pa lori ẹsun pe akẹkọọ naa atawọn akẹgbẹ rẹ pe oun ni were.”
O fikun pe ọkunrin naa yoo fara mọ wọn titi iwadi yoo fi pari.












