Ọmọ ọdún 13 tí mo fẹ́ lọ́jọ́sí ti ń kẹ́kọ̀ọ́ gboyè 'Masters' lókè òkun - Ahmed Yerima

Aworan Sẹnetọ Yerima

Gomina tẹlẹri nipinlẹ Zamfara, Sẹnẹtọ Ahmed Yerima ti ni gbeyawo kii se idaduro atikẹkọọ awọn ọmọbinrin.

Yerima sọ eleyi lasiko to n sọrọ lori bi ẹnu se kun un nigba to gbe majeṣin ọmọ ọdun mẹtala kan ati orilẹede Egypt niyawo lọdun 2010.

Ọpọ awọn ọmọ orilẹede Naijria lo bu ẹnu atẹ lu igbesẹ yii nigba naa to bẹẹ ti ile igbimọ asofin apapọ fi gbe iwadi kalẹ lori rẹ.

Lẹyin ọdun mẹwaa ti igbayawo naa waye, Yerima kede fun aye lori ẹrọ mounhmaworan pe Iyawo oun ọjọsi ti dagba bayi.

Gomina tẹlẹ ni ipinlẹ Zamfara ọhun ṣalaye pe ọmọdebinrin naa ti n kẹkọọ gboye imọ keji ni fasiti, iyẹn 'Masters'

Ninu ifọrọwerọ rẹ, Yerima bu ẹnu atẹ lu iwe ofin United Nation lori ọmọde ti ọdun 2003 ati iwe ofin fun ijiya awọn eeyan ti ọdun 2015, ti orilẹede Naijira n tẹle.

'Igbeyawo ko da ile ẹkọ duro. '

Gomina tẹlẹ naa ni Igbeyawo ko ni nnkan se pẹlu ile ẹkọ lilọ nitori wọn ko di arawọn lọwọninu iwoye tirẹ.

O fi kun un pe iyawo ti oun fẹ to da ija silẹ lọdun mẹwaa sẹyin, ti wa ni ipele Master ni ile ẹkọ rẹ loke okun.

O tẹsiwaju pe ọmọ oun toun fi lọkọ ni ọmọ ọdun mẹrindinlogun n se PhD bayii niluu London.

Yerima ni oun ko ri nnkan to buru ninu sise igbeyawo ni isẹsẹ aye obinrin.

"To ba ti mọ pe wa mu wọn tẹsiwaju ninu ẹkọ wọn, ko si nnkan to n da eeyan duro lati tẹsiwju ninu ẹkọ lẹyin igbeyawo."

Gẹgẹ bi o se sọ, o ni oun ko tapa si ofin kankan bi oun se se igbeyawo pẹlu majeṣin naa, ti oun si ti kọ eti ikun si gbogbo ọrọ ti awọn eeyan n sọ nita.

"Gbogbo nnkan to ba yẹ ko se fun igbeyawo wa labẹ ofin Sharia. O gbọdọ pese ile fun ọmọ to fẹ fẹ sile , iyẹn ni ofin ti orilẹede Egypt gbe kalẹ."

Bi Yerima ṣe gbe majeṣin ọmọ ilẹ Egypt niyawo lọdun 2010

Ni Ọdun 2010, iroyin nipa Igbeyawo Sẹnẹtọ Yerima ati ọmọdebinrin ọmọ ọdun mẹtala kan lati orilẹede Egypt tan kaakiri agbaye.

Sẹnẹtọ Yerima, ẹni ọdun mọkandinlaadọta lọdun naa jẹ gomina ni ipinlẹ Zamfara nigba naa,

O ni ọmọdebinrin naa ti oun fẹ gẹgẹ bi iyawo kẹrin ki i se ọmọ ọdun mẹtala lasiko ti oun fẹ silẹ bi o tilẹ je pe o kọ lati sọ ọjọ ori rẹ lasiko to fẹ.

ninu iwadi ti BBC ṣe nigba naa, agbẹnusọ fun ileeṣẹ aṣoju ijọba ilẹ Egypt ni Naijiria nigba naa sọ pe ile ẹkọ ni ọmọdebinrin naa wa lorilẹede wọn ki wọn to mu u wa lọkọ ni Naijiria.

Igbeyawo Yerima pẹlu ọmọ ọdun mẹtala yii kọ ni akọkọ.

Ṣaaju lọdun 2006, iroyin kan ti kọkọ gbe e jade pe o se igbeyawo pẹlu ọmọ mẹẹdogun kan.