Àjọ NATO kùnà láti sọ pàtó àkókò tí Ukraine yóò darapọ̀

Oríṣun àwòrán, EPA
Ajọ awọn orilẹede NATO ti sọ pe orilẹede Ukraine le darapọ mọ ajọ naa.
Amọṣa wọn ni o di igba “ti awọn ọmọ ẹgbẹ naa ba ti fẹnuko ti o si ti mu gbogbo odod ṣẹ”.
Ajọ NATO sọ eyi lẹyin ti aarẹ orilẹede Ukraine, Volodymyr Zelensky ti bu ẹnu atẹ lu bi wọn ṣe n fi ẹse falẹ pẹlu eto didarapọ Ukraine mọ ajọ ọhun.
Ninu atẹjade kan, NATO ni lootọ loun mọ pe o yẹ ki igbesẹ naa tubọ ya kankan sii ṣugbọn oun ko le sọ ni pato igba ti yoo jẹ.
Ṣaaju, aarẹ Zelensky ti kọkọ kegbajare sita pe ko daju pe ajọ NATO fẹ ki Ukraine darapọ.
Aarẹ Zelensky wa lorilẹede Lithuania bayii nibi ti Ipade ajọ naa ti n waye ni ilu Vilnius.
Orilẹede Ukraine ni lootọ loun gba pe oun ko le darapọ lasiko ti ogun oun ati Russia ṣi n gbona girigiri, amọṣa oun n fẹ igbesẹ kanmọ kia lati darapọ ni kete ti ogun naa ba pari.








