Àkàrà tú sépo! obìnrin kan fẹ́ pa Zelensky, Ààrẹ Ukraine, àṣìrí tú 

Aworan Afurasi ati awon ologun

Oríṣun àwòrán, SBU

Ileeṣẹ ẹsọ alabo lorilẹede Ukraine ni ọwọ ti tẹ obìnrin kan to n peto gbero lati ran orilẹede Russia lọwọ lati ṣeku pa Aarẹ Volodymyr Zelensky.

Ileeṣẹ naa ni obìnrin ọhun n se iwadi saaju irinajo Aarẹ lọ si agbegbe Mykolaiv, ti omiyale ti waye ninu oṣu kẹfa.

Ukraine ni ọpọ igba tni awn ti fi ẹsun kan awọn araalu kan pe wọn n fọwọsowọpọ pẹlu awọn ọmọ ologun Russia.

Zelensky fidi rẹ mulẹ pe oun ti gbọ si igbesẹ ileeṣẹ ẹsọ alabo naa lati gbogun ti awọn ọdalẹ ọhun.

Amọ orilẹede Russia ko ti sọrọ lori iṣẹlẹ yii.

Aworan Aare Zelensky

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ileeṣẹ ẹsọ alabo Ukraine, SBU ni oun gba obìnrin naa mu lasiko to n fi ọrọ asiri ransẹ si Russia

Ileeṣẹ ẹsọ alabo Ukraine, SBU, ninu atẹjade kan ni awọn gba obìnrin naa mu lasiko to n fi ọrọ ransẹ si Russia.

Bakan ni wọn fi aworan obìnrin ọhun síta lasiko ti ọwọ tẹ.

Gẹgẹ bii SBU ṣe sọ, afurasi ọhun lo n gbe ni agbegbe Ockakiv, ibi tí Aarẹ Zelensky ti ṣe abẹwo si ninu oṣu keje, to si fẹ da ikọ ologun silẹ nibẹ.

Iroyin fi ye wa pe, Ileeṣẹ ẹsọ alabo ko mu obinrin naa lasiko ti Aarẹ ṣe abẹwo sugbọn wọn gbe igbesẹ to yẹ lati dena ikọlu.

Awọn osisẹ ẹsọ alabo tẹlẹ obinrin naa lati mọ si nípa rẹ, tí iwadii si fihan pe orilẹede Russia lo n sisẹ fun.

Obinrin naa ni igbagbọ wa pe yoo foju ba ileęjọ lori ẹsun pe o n pin iroyin nípa ileeṣẹ ologun to ko ni Ibuwọlu ijọba kiri.

Igbagbọ wa pe yoo lo ọdun mejila lọgba ẹwọn tí ileẹjọ ba ri pe o jẹbi.