Iyán ogún ọdún jó Keyamo àti El-Rufai lọ́wọ́ lásìkò àyẹ̀wò fún ipò mínísítà

El-Rufai ati Keyamo

Oríṣun àwòrán, Collage

Ijoko awọn sẹnetọ di ariyanjiyan lọjọ Aje lasiko ti wọn n ṣe ayẹwo ati ifọrọwanilẹnuwo fun ẹnikan lara awọn ti aarẹ fẹ yan sipo minisita, Festus Keyamo.

Keyamo, to fi igba kan jẹ minisita kekere fun ọrọ awọn oṣiṣẹ ati igbani siṣẹ lasiko ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari, farahan niwaju ile aṣofin naa ni ọsan ọjọ Aje, fun ipo tuntun labẹ ijọba Bola Tinubu.

Ṣugbọn ṣa, ọrọ di ariyanjiyan nigba ti sẹnetọ to n sọju ẹkun idibo Abia Central, Darlington Nwokocha, da aba pe ki wọn so ayẹwo Keyamo rọ na.

Nwokocha fi ẹsun kan Keyamo pe o fi abuku kan awọn aṣofin lasiko to fi kọkọ jẹ minisita.

Bakan naa lo tun sọrọ nipa ẹsun iwa ibajẹ ti wọn fi kan Keyamo , ati bo sẹ kọ lati farahan niwaju awọn aṣofin lọdun 2020 lori ẹsun naa to ni i ṣe pẹlu eto igbani siṣẹ fun 774,000 ọmọ Naijiria fun akanṣe iṣẹ lọdun naa.

Ọrọ igbanisisẹ da wahala silẹ laarin Festus Keyamo ati awọn ọmọ ile aṣofin

Ninu oṣu Kẹrin ọdun 2020, ijọba apapọ buwọlu eto igbani siṣẹ naa, pẹlu ilana lati gba ẹgbẹrun kan eeyan lati ijọba ibilẹ kọọkan.

Igbesẹ naa ni wọn lo jẹ ara ọna lati din ipa ajakalẹ aarun Covid-19 ku lara araalu.

Ọrọ iṣẹ naa da wahala silẹ laarin Festus Keyamo ati awọn ọmọ ile aṣofin, paapaa nitori bi awọn kan ṣe fi ẹsun kan-an pe magomago wa ninu eto naa.

Senetọ Nwokocha sọ pe wọn gbọdọ da ayẹwo Keyamo duro, titi di igba to ba yanju awọn ẹsun naa.

Ọrọ naa pada di ariwo laarin awọn sẹnetọ nitori pe wọn ko le fẹnuko lori boya ki wọn o tẹle aba naa tabi bẹẹ kọ.

Aile fi ẹnu ko wọn ọhun si lo mu ki aarẹ ile aṣofin, Sẹnetọ Godswill Akpabio, so ijoko ile rọ.

Keyamo tọrọ aforijin lọwọ ijoko ile asofin agba, ki wọn to se ayẹwo fun

Irọlẹ patapata ni awọn aṣofin naa to pada si ori ijoko wọn lati tẹsiwaju pẹlu eto ayẹwo naa.

Wọn si yanju ifọrọwanilẹnuwo fun Keyamo lẹyin to tọrọ aforiji lọwọ awọn aṣofin naa, to si tun ṣalaye bi aigbọra ẹni ye lasiko igbaniṣiṣẹ naa ṣe fa ikunsinu.

Ayẹwo Festus Keyamo ni awọn aṣofin fi pari eto ayẹwo fun awọn ti Aarẹ Tinubu fi orukọ wọn ranṣẹ.

Ayẹwo Keyamo nikan kọ ni awọn aṣofin da duro, awọn aṣofin naa ko ti i buwọlu iyansipo gomina ipinlẹ Kaduna tẹlẹ, Mallam Nasir El-Rufai.

Oun nikan kọ, awọn meji mii Sani Abubakar Danladi lati ipinlẹ Taraba ati Stella Okotete lati Delta.

Aarẹ ile aṣofin agba Sẹnẹtọ Godswill Akpabio,sọ pe awọn n reti abọ iwadii awọn agbofinro lori awọn eeyan mẹta wọnyi ki wọn to le ṣayẹwọ wọn sipo minisita ni ibamu pẹlu ofin.

Lati ọjọ Aje to kọja ti wọn ti bẹrẹ ayẹwo ni wọn ti forukọ wọn ranṣẹ amọ ko pada siwaju ile debi pe wọn yoo kede wọn pẹlu awọn marundinlaadọta yoku.

Wo orukọ awn eeyan marundinlaadọta to fẹ gba ipo Minisita

Orukọ awọn ti ile ti ṣayẹwo fun ree gẹgẹ bi Sẹnẹtọ Godswill Akpabio ti ṣe ka wọn jade:

  • Abubakar Momoh - Edo
  • Betta Edu - Kuros Riba
  • Uche Nnaji - Enugu
  • Joseph Utsev - Benui
  • Hannatu Musawa - Katsina
  • Nkeiruka Chidubem Onyejocha - Abiya
  • Stella Okotete - Delta
  • Uju Kennedy-Ohanenye - Anambra
  • Ahmed Dangiwa - Katsina
  • Olawale Edun - Ogun
  • Imaan Suleman Ibrahim - Nasarawa
  • Bello Muhammad Goronyo - Sokoto
  • Nyesom Wike - Rivers
  • David Umahi - Ebonyi
  • Mohammad Badaru Abubakar - Jigawa
  • Lateef Fagbemi - Kwara
  • Doris Aniche Uzoka - Imo
  • Yusuf Maitama Tuggar - Bauchi
  • Professor Ali Pate - Bauchi
  • Ekerikpe Ekpo - Akwa Ibom
  • Mohammed Idris - Nigeria
  • Olubunmi Tunji Ojo - Ondo
  • Dele Alake - Ekiti
  • Waheed Adebayo Adelabu - Oyo
  • John Eno - Profit Cross
  • Abubakar Kyari - Borno
  • Abdullahi Tijjani Gwarzo - Kano
  • Dr Mariya Bunkure - Kano
  • Isaac Salako - Ogun
  • Bosun Tijjani - Ogun
  • Tunji Alausa - Lagos
  • Tanko Sununu - Kebbi
  • Adegboyega Oyetola - Osun
  • Atiku Bagudu - Kebbi
  • Bello Matawalle - Zamfara
  • Ibrahim Geidam - Yobe
  • Simon Lalong - Plato
  • Lola Adejo - Lagos
  • Shuaibu Abubakar - Kogi
  • Tahir Mamman - Adamawa
  • Aliyu Sabi Abdullahi - Nigeria
  • Judge Ahmed Saidu - Gombe
  • Heneken Lakpobiri - Bayelsa
  • Father Maigari - Taraba
  • Zephaniah Jissalo - Abuja