Màá gbé àwọn tó fẹ̀sùn kàn mí pé mò ń kọ ìdájọ́ Tribunal lórí ìbò ààrẹ lọ sílé ẹjọ́ - Fasola

Oríṣun àwòrán, Babajide Sanwo-Olu
Minisita ana fun iṣẹ ode ati ile gbigbe, Babatunde Fashola ti fọhun lori ọrọ kan to n milẹ kaakiri ori ayelujara pe oun ti n kọ idajọ igbimọ to n ri si awuyewuye to waye lẹyin idibo Aarẹ ọdun 2023.
Fashola lo sọrọ soke nitori bi awọn eeyan ṣe n sọ lori ayelujara pe oun atawọn agbẹjọro kan to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ti n kọ idajọ ọhun, eyii ti wọn yoo fun awọn adajọ.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ Fashola, iyẹn Hakeem Bello fisita, o ni Fashola ti sọ pe iroyin ẹlẹjẹ ni ọrọ naa.
O ti wa ke si awọn agbofinro ki wọn ṣe ohun to yẹ si awọn to n gbe irufẹ iroyin ẹlẹjẹ bẹẹ kiri.
Irọ́ gbu u ni pé mò ń kọ ìdájọ́ ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò ààrẹ - Fasola fọnmú
Fasola sọ siwaju si pe oun ko tilẹ si niluu Abuja lasiko yii, o si bu ẹnu atẹ lu awọn to n pin iroyin ọhun lori ayelujara.
Fashola ni oun ti bẹrẹ igbesẹ lati pe awọn to kọ ọrọ naa jade loju opo X lẹjọ, to fi mọ awọn ileesẹ iroyin to jẹ ki ọrọ naa gbilẹ sii.
Bakan naa ni Fasola ni ileeṣẹ to n bojuto eto ibaraẹnisọrọ ni Naijiria, NCC yoo tun da si ọrọ naa.
Bi ọrọ naa ṣe bẹrẹ si n tan ka ree...
Awọn eeyan bẹrẹ si n jẹ orukọ Fashola lẹnu lẹyin ti ẹnikan lori Twitter sọ pe Fashola ti bẹrẹ si n kọ idajọ naa.
Ọkunrin to kọ atẹjade naa, ti orukẹ rẹ n jẹ Jackson Ude fi kun pe erongba Aarẹ Bola Tinubu ati APC ni lati gbe idajọ naa le adajọ to n gbọ awuyewuye to waye lasiko ibo Aarẹ lọwọ lẹyin ti Fahsola ba kọ idajọ ọhun tan.
Atẹjade Ude sọ pe “Gomina ipinlẹ Eko ati minisita fun iṣẹ tẹlẹ, Babatunde Fashola atawọn agbẹjọro kan nin ẹgbẹ oṣelu APC n gbero lati kọ idajọ igbimọ to n gbọ awuyewuye to waye lasiko ibo.”
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
“Fashola ni a gbọ pe o dari bi wọn ṣe ṣe magomago idibo Aarẹ ọdun 2023 ki Bola Tinubu le jawe olubbori.”
“A tun gbọ pe oun kan naa lo kọ idajọ igbimọ to ri si awuyewuye ibo Aarẹ to waye lọdun 2019, ninu eyi ti Muhammadu Buhari ti bori.”
“Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, Fashola n ṣiṣẹ takuntakun lati pari idajọ to n kọ lọwọ ko le gbe le igbimọ naa lọwọ.”
“Yatọ si owo ti wọn fẹ fun awọn adajọ igbimọ naa, wọn tun ti ṣeleri fun awọn adajọ ọhun pe wọn yoo fun wọn ni igbega si ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria ti wọn ba le gba idajọ ti Fashola nkọ.”
Wayi o, Fashola ti sọ pe ko si nnkan to jọ bẹẹ.















