Ààrẹ Tinubu ṣe àfikún iye owó ètò ìṣúná fún ọdún 2025

Oríṣun àwòrán, @Jidesanwoolu
Aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Ahmed Tinubu ti kesi ile igbimọ aṣofin fun aṣẹ lati se afikun si iye owo isuna fun ọdun 2025 lati N49.7 trilọnu si N54.2 trilọnu.
Eyi lo wa ninu lẹta kan ti aarẹ kọ si ile igbimọ aṣofin agba ti Aarẹ Sẹnetọ Godswill Akpabio si ka fun gbogbo ọmọ ile igbimọ aṣofin lọjọbọ, ọjọ karun un oṣu keji ọdun 2025.
Ninu lẹta naa, Aarẹ ni ibere yii lo ṣe koko lati mu ilọsiwaju ba awọn ẹka ijọba kan.
Aarẹ ni ẹka ijọba to n pa wo wọle(FIRS) nilo N1.4tr, N1.2tr fun ileeṣẹ aṣobode ati N1,8tr fun awọn ẹka ijọba yooku.
Lẹyin to ka lẹta naa, Aarẹ ile igbimọ aṣofin agba kesi igbimọ to n risi eto iṣuna lati bẹrẹ gbayẹwo ibere aarẹ.
Bẹẹ ba gbagbe, Ninu oṣu kejila ni Aarẹ Bola Tinubu gbe eto iṣuna ọdun 2025 lọ siwaju ile aṣofin l'Abuja.
Lasiko ijokoo ile l'Ọjọru ni Tinubu gbe eto iṣuna to pe ni eto iṣuna ipadabọsipo, alaafia ati ọrọ lọ siwaju awọn aṣofin.
N47.96tn ni gbogbo iye owo ti ijọba apapọ Naijiria fẹ na lọdun 2025 gẹgẹ bi Tinubu ṣe gbe e kalẹ niwaju ile aṣofin.
Aarẹ Tinubu sọ fawọn aṣofin pe eto iṣuna naa yoo jẹ ki ọwọngogo nnkan lọlẹ lati ida 34% to wa lọ si ida 15% lọdun 2025.
Bakan naa ni Tinubu tun sọ pe owo dọla si naira yoo tun walẹ sii lati N1,700 to wa bayii lọ si N1,500.
Aarẹ Naijiria fikun ọrọ rẹ pe agba epo rọbi ti Naijiria n pese lojumọ fun tita yoo di 2.06m lọdun 2025.
N34.82tn ni owo ti Tinubu sọ pe ijọba n reti lati pa wọle lọdun 2025.
N47.90tn ni owo ti Aarẹ Tinubu sọ pe ijọba oun yoo na lọdun 2025 nigba ti N15.81tn yoo ba sisan ele owo gbese ti Naijiria jẹ lọ.















