Ìdí ti ìgbìmọ̀ Alálàájì NAHCON fi sún gbèdéke owó sísan fún ìrìnàjò Hajj ọ́dún 2025 síwájú

Aworan awọn alalaaji ni Mecca

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Alaga igbimọ NAHCON to n ri si irinajo awọn ọmọ Naijiria lọ si ilu Mecca lati lọ sin Ọlọrun Allah, Ọjọgbọn Saleh Usman, ti kede pe ajọ naa ti sun gbedeke iforukọsilẹ fun eto Alalaaji ọdun 2025 siwaju.

Ọpọ eeyan to fẹ rinrin ajo lọ si Mecca lọdun yii ni ko lanfaani lati forukọ silẹ titi ti gbedeke ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu Kinni fi pe.

Ni Ọjọrọ ọjọ karun un oṣu Keji ni alaga ajọ NAHCON ṣalaye wi pe awọn ti sun gbedeke fun iforukọsilẹ fun eto Hajj ọdun yii si ọjọ kẹwaa oṣu Keji bayii.

Ọjọgbọn Usman ni igbesẹ yii ko ṣẹyin bi ọpọ eeyan ti n bẹbẹ nitori awọn eeyan ti wọn ko le pari iforukọsilẹ titi ti gbedeke ọjọ kọkanlelọgbọn fi kọja.

Alaga ajọ NAHCON wa rọ gbogbo akọwe agba ajọ naa lawọn ipinlẹ lati tete fi owo awọn to n rinrin ajo lọ si Hajj ranṣẹ tori kawọn le lowo naa lati gba ile ti wọn yoo de si ni Mecca.

Ọjọgbọn Usman sọ ninu atẹjade ti ajọ NAHCON fi sita lati kede gbedeke tuntun ọjọ lati forukósilẹ fun eto Hajj ọdun 2025 pe ọjọ kẹrinla oṣu Keji yii ni adehun ti ajọ naa ni pẹlu Saudi Arabia lori ọrọ iforukọsilẹ awọn musulumi to fẹ lọ ṣiṣẹ Hajj ni Mecca lọdun yii.

O ni eyi tumọ si pe gbogbo owo tawọn eeyan ba fẹ san lati Naijiria gbọdọ ti de inu akaunti ijọba Saudi ṣaaju ọjọ kẹrinla oṣu Keji yii.

Ninu ọrọ tiẹ, oludari eto alalaaji, Ọmọba Anofiu Elegushi, sọ awọn to ba lowo lati sanwo Hajj yatọ si $500 owo ti wọn gbọdọ ni lọwọ lasiko irinajo lati sanwo wọn.

O ni o san ki wọn lọ wa $500 ti wọn gbọdọ ni lọwọ lasiko irinajo lọtọ ki ọkan ma baa pa ọkan lara.

Bakan naa ni akọwe agba eto alalaaji ni ipinlẹ Kebbi, Alhaji Faruku Yaro, rọ awọn akẹgbẹ rẹ lawọn ipinlẹ yooku lati tete fi owo awọn arinrinajo Hajj ranṣẹ tori awọn ti wọn ko ba tete sanwo le ma lanfaani lati rinrin ajo lọ si Mecca lọdun yii.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Wo iye owó tí o nílò láti lọ Hajj lọ́dún 2025 yìí

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ṣaaju ni ajọ NAHCON to n ri si ọrọ irinajo Hajj si ilẹ mimọ niluu Mecca ti kede iye tawọn eeyan to ba fẹ lọ si Saudi Arabia lọdun yii yoo san.

Ninu ifọrọwerọ ti o ṣe pẹlu BBC, alaga ajọ NAHCON, Ọjọgbọn Abdullahi Saleh Usman Pakistan, ṣalaye pe irin-ajo Hajj ti ọdun 2025 yii pin si ọna mẹta.

Ọjọgbọn Abdullahi ṣalaye pe owo tawọn ẹlẹsin musulumi to ba fẹ lọ Mecca lati apa guusu orilẹede Naijiria yoo pọ ju tawọn eeyan to ba fẹ lọ lati ẹkun ila-oorun ariwa ati iwọ -oorun ariwa lọ.

Alaga NAHCON ni awọn to ba fẹ lọ si Mecca lati awọn ipinlẹ to wa ni apa iwọ oorun ariwa Naijiria bii Kano, Kaduna, Jigawa, Katsina, Zamfara, Sokoto ati Kebbi yoo san N8,457,685.59.

Bakan naa ni o sọ pe awọn musulumi to ba fẹ lọ Mecca lati awọn ipinlẹ to wa ni apa ila oorun ariwa Naijiria bii Adamawa, Yobe, Borno, Gombe, Bauchi ati Taraba yoo san N8,327,127.59 fun irin-ajo Hajj.

Alaga ajọ NAHCON ni awọn musulumi to ba fẹ lọ Hajj lati awọn ipinlẹ to wa lapa guusu Naijiria yoo san N8,784,85.59 fun owo Hajj wọn.

Ọjọgbọn Abdullahi ni owo Hajji ọdun 2025 yii fi diẹ ju ti ọdun 2024 lọ.

''Ẹru tiẹ kọkọ ba wa tori a ti ro pe owo Hajj ọdun yii maa ti muliọnu mẹwaa naira ni tabi ko ju bẹẹ lọ.

Amọ, pẹlu iranlọwọ Ọlọrun atawọn igbesẹ kan ti a gbe, o pada jẹ irọrun fun wa.

A tun ti ṣeto fun adinku inawo awọn alalhaji ti yoo wa ni Mina ki o le rọrun fun wọn,'' Ọjọgbọn Abdullahi lo sọ bẹẹ.

Alaga NAHCON ko ṣai fidi rẹ mulẹ pe ko si iranwọ owo lati ọdọ ijọba lori owo Hajj yii.

O fikun ọrọ rẹ ẹẹdẹgbẹta owo dọla ni awọn alalhaji yoo gba lọdun yii lati fi ra nnkan ti wọn ba nilo nibi iṣẹ Hajj.

Ọjọgbọn Abdullahi ni ajọ NAHCON ti ṣeto gidi ki iru nnkan to ṣẹlẹ lọdun to lọ ni Mina ma ba le ṣẹlẹ lọdun yii.