Ọkùnrin kan jóná mọ́ inú ọkọ̀ ní Kwara

OKUNRIN TO JONA NINU MOTO

Oríṣun àwòrán, KWARA FIRE SERVICE

Ọkùnrin kan tí pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ sọ́wọ́ ìjàm̀bá iná nínú ọkọ̀ ní ìpínlẹ̀ Kwara.

Ìjàm̀bá iná náà wáyé lẹ́nu ọ̀nà ilé iṣẹ́ tó ń pèsè omi inú ọ̀rá kan ní agbègbè Egbejila, òpópónà Airport ni ìlú Ìlọrin.

Àtẹ̀jáde kan tí Agbẹnusọ iléeṣẹ́ panápaná ìpínlẹ̀ Kwara Hakeem Hassan Adekunle fi síta lọ́jọ́bọ̀ Kejìdínlọ́gbọ̀n, oṣù Keje, ọdún 2022 ní nǹkan bíi ago mẹ́sàn-án ku ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dógún ọjọ́rú ni ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà wáyé.

Adekunle ní olóògbé náà, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Emmanuel jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógójì.

Ó ṣàlàyé pé ohun tó ṣokùnfà ìjàm̀bá iná náà kò ṣẹ̀yìn bí Emmanuel ṣe ra epo bẹntiróòlù ọgbọ̀n lítà sínú gálọ̀nù mẹ́ta tó sì gbé sínú ọkọ̀.

Ó ní lẹ́yìn tó gbé àwọn epo bẹntiróòlù náà sínú ọkọ̀ tán ló yí gbogbo gíláàsì ọkọ̀ sókè àmọ́ ọkọ̀ náà ṣàdédé gbiná nígbà tó dé ẹnu ọ̀nà ibi iṣẹ́ rẹ̀.

Ó fi kun pé ohun tó jẹ́ kí ọkọ̀ náà gbiná ṣókùnkùn díẹ̀ àmọ́ ó ṣeéṣe kó jẹ́ wí pé ooru àpọ̀jù inú ọkọ̀ náà ló fà á.

Bákan náà ló ní àwọn ti gbé òkú ọkùnrin náà le alákòso ilé iṣẹ́ omi inú ọ̀rá náà lọ́wọ́, ẹni tó jẹ́ ọ̀gá Emmanuel.

Ó wà pàrọwà sáwọn ènìyàn láti máa ṣọ́ra ṣe pàápàá lórí dídá ààbò bo ẹ̀mí àti dúkìá wọn.