Erémọdé lásán làwọn tó ní àwọn yóó yọ Buhari nípò ń ṣe, wọn ò tó bẹ́ẹ̀ - Ìjọba àpapọ̀

Femi Adesina

Oríṣun àwòrán, @NewsAf24

Ijọba apapọ ti sọ pe eremọde lasan lawọn aṣofin to fun Aarẹ Muhammadu Buhari lọsẹ mẹfa pere lati yanju iṣoro to n koju eto abo n ṣe.

Ṣaaaju lawọn aṣofin naa, to wa ninu ẹgbẹ alatako, ti kọkọ binu jade kuro ninu ile igbimọ aṣofin, ti wọn si sọ pe awọn yoo bẹrẹ igbesẹ lati yọ Aarẹ Buhari nipo ayafi to ba wa ọna abayọ si eto abo to mẹhẹ.

Nigba to n fẹsi si ohun ti awọn aṣofin naa ṣe lori ikanni ileeṣẹ iroyin Channels, agbẹnusọ Buhari, Femi Adesina sọ pe eremọde lasan lawọn aṣofin na n ṣe, nitori ko si nnkankan ti wọn yoo danwo lẹyin idunkoko wọn.

O ni awọn to sọ pe awọn yoo yọ Buhari nipo ko lẹnu ninu ile igbimọ aṣofin.

Adesina sọ pe awọn eeyan le maa sọrọ gẹgẹ bi ofin ṣe gba wọn laye amọ ko si nnkan miran ti wọn yoo lẹyin ọrọ ti wọn ba sọ, beẹ si ni ko si ara miran ti wọn yoo da da idunkoko naa.

O ni “Wọn mọ ninu ọkan wọn pe wọn ke le ṣe ohun ti wọn sọ, wọn kan n fi akoko orilẹ-ede yii ṣofo ni, bẹẹ naa ni wọn n fi akoko ile igbimọ aṣofin ṣofo nitori wọn ko le ṣe aṣeyọri ohun ti wọn n gbero.”

“Otitọ to wa nibẹ ni pe, awọn ti ko lẹnu ninu ile igbimọ aṣofin yoo maa pariwo ẹnu, nigba to jẹ pe awọn to lẹnu nikan lo maa n ṣaṣeyọri ninu ile.”

Bo tilẹ jẹ Adesina ni lootọ lo yẹ ki ọrọ eto abo jẹ awọn ọmọ Naijiria logun, ọrọ naa ka awọn aṣofin ọhun lara nitori pe ọrọ naa ti n kan wọn gbọngbọn.