Kí ló ṣẹlẹ̀ tí ìró ìbọn tún fi ń dún lákọlákọ nílùú Owo?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iro ibọn tun ti dun lakọ-lakọ niluu Owo, nipinlẹ Ondo lalẹ Ọjọru.
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa lo fidi iroyin naa mulẹ loju op Twitter rẹ..
Gẹgẹ bii ohun ti wọn sọ, awọn to farapa nibi iṣẹlẹ naa ti wa nile iwosan bayii fun itọju.
Atẹjade ti ọlọpaa fi lede oju opo Twitter ọhun ni “Lalẹ oni, awọn eeyan kan ṣina ibọn bole nileeṣẹ Craneburg Construction Company to wa niluu Owo.”
“Awọn ọlọpaa ti wa nibẹ bi a ṣe n sọrọ yii, wọn si ti gbe awọn to farapa lọ sile iwosan, ara wọn si ti n balẹ.”
Lẹyin atẹjade naa ti ọlọpaa fi lede ni nnkan bii aago mẹwaa abọ aṣalẹ lawọn araalu bẹrẹ si n bere ẹkunrẹrẹ ohun to ṣẹlẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni Naijiria, Olumuyiwa Adejobi sọ fun awọn akọroyin pe ki wọn fun alukoro ileeṣẹ naa nipinlẹ Ondo, Funmilayo Odunlami laafani lati ṣe iwadii ko le ṣalaye ohun to ṣẹlẹ ni pato.
Ti ẹ ko ba gbagbe, ọjọ karun un, oṣu Kẹfa, ọdun 2022 yii lawọn agbebọn kan kọlu ile ijọsin St Francis Catholic to wa ladugbo Owaluwa niluu Owo yii kan naa.
Ogoji eeyan lo ba iṣẹlẹ naa lọ laarin ọjọ diẹ siwa wọn, nigba ti ọpọ awọn mii farapa yanayana.












