Àṣìṣe gba adé ipò kẹta lọ́wọ́ Naijiria lópin WAFCON 2022

Ifẹsẹwọnsẹ Naijiria ati Zambia

Ẹgbẹ agbabọọlu obìnrin ti orile-ede Naijiria, Super Falcons, ko ri ami ẹyẹ kankan gba pada sile ni idije bọọlu àwọn obìnrin ni Africa, wafcon to waye ni Morocco.

Eyi waye lẹyin ti orile-ede Zambia na wọn ni ami ayo kan si odo níbi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ to waye lọjọ Ẹti fun ipo kẹta idije naa.

Papa ìṣeré Mohammed V n'ilu Casablanca lo ti waye.

Ọmi odo ni wọn kọ́kọ́ ta, sugbọn ọmọ ẹgbẹ́ agbabọọlu Super Falcons, Nnadozie Chiamaka, ṣeeṣi gba bọọlu si àwọ̀n wọn, eyi to di goolu ọ̀fẹ́ fun Zambia, ni isẹju kọkandinlọgbọn.

Zambia gba ipo kẹta

Ko si ẹni to pada gba bọọlu si àwọ̀n ara wọn titi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ fi pari.

Ninu ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ mẹfa ti Naijiria gbá ni wafcon 2022, mẹta pere ni wọn bori.

Wọn lu Botswana ati Burundi ni ipele akọkọ.

Wọn lu Cameroun ni ipele quarter final.

Sugbọn South Africa lu wọn ní ipele akọkọ, Morocco lu wọn ni ipele semi final.

Zambia lu wọn ni aṣekagba, to si gba ipo kẹta mọ wọn lọwọ.

Igba kẹta rèé ti Naijiria padanu ife ẹyẹ ni wafcon lati igba tó ti bẹ̀rẹ̀.

Amọ o gba a nigba mẹsan-an ninu mejla.

Bi o tilẹ jẹ pe Super Falcons ko ṣe àṣeyọrí ni wafcon ọdun yii, yoo lanfaani lati kopa ni idije ife agbaye lọdun 2023, ni Australia ati New Zealand.

Nigba to ba awọn akọroyin sọ̀rọ̀ lẹyin ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ third place, olukọni Super Falcons, Randy Waldrum sọ pe lootọ ni awọn ko ri ipo kankan mu ni idije naa, botilẹ jẹ pe awọn gbiyanju.

O ni sugbọn idunnu to wa nibẹ ni pe àwọn lanfaani lati ri tikẹẹti idije fun ife agbaye gba.

Ati pe gbogbo aṣiṣe ti awọn ṣe ni awọn yoo ṣe àtúnṣe si ṣáájú idije to n bọ.

Ọdun to kọja ni Waldrum gba iṣakoso gẹgẹ bi olukọni Super Falcons.

Naijiria ati Zambia
Nàìjíríà àti Zambia yóò kojú ara wọn lónìí fún ipò kẹta wafcon 2022
Agbabọọlu Zambia ati Super Falcons

Oríṣun àwòrán, cafonline

Orile-ede Naijiria ati Zambia yoo koju ara wọn lónìí lati jà fun àmì ẹyẹ bàbà (ipo kẹta) ninu idije bọọlu àwọn obìnrin ni Africa to n lọ lọwọ ni Morocco.

Orile-ede mejeeji padanu ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ti wọn gbá ni ipele semi final lọjọ Aje.

Naijiria padanu 5-4 ninu pẹnariti ti wọn gba lẹyin ti ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn pẹlu Morocco yọrí si 1-1 lẹyin wakati meji.

Ami ayo 1-0 ni Zambia gba pẹlu South Africa.

Aago mẹsan-an alẹ oni ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa yoo waye, ni papa ìṣeré Mohammed V, n'ilu Casablanca.

Kí ni àtimáaṣebọ̀ Super Falcons ní ìdíje WAFCON?

Super falcons

Oríṣun àwòrán, cafonline

Naijiria ti gba ife idije WAFCON fun igba mẹsan-an, ninu mọkanla to ti waye sẹ́yìn.

Ọdun 2018 ni wọn gba a kẹhin.

Ẹni ti yoo gba eyi to n lọ lọwọ wà laarin South Africa ati Morocco.

Ko si ẹni to gba a ri ninu orile-ede mejeeji.