Àwọn ọlọ́pàá kan ń fapá jánú lórí àìsan owó àjẹ́mọ́nú ìdìbò Osun, iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ẹ̀bi àwọn kọ́,ẹ̀bi báǹkì táwọn ọlọ́pàá náà ń lò ni

Awọn ọlọpaa lẹnu iṣẹ nipinlẹ Ọṣun

Ni owurọ ọjọ Ẹti ni iroyin kan wọle sigboro pe awọn ọlọpaa kan ti wọn kopa ninu eto idibo to waye nipinlẹ Ọṣun lọjọ kẹrindinlogun ọdun 2022 ni wọn ti n fi ẹhonu han pe gbogbo owo ajẹmọnu to tọ si wọn ni wọn ko tii ri gba lẹyin ti eto idibo naa ti kọja lọ.

Awọn iroyin to jade lawọn iwe iroyin abẹle kan n sọ pe awọn ọlọpaa naa n fi apapjanu pe awọn adari ileeṣẹ ọ̀lọpaa kuna lati san owo ounjẹ atawọn ajẹmọnu miran lasiko idibo naa ti wọn si n ke si ijọba apapọ, paapaajulọ aarẹ Buhari lati boju wo ọr naa.

Esi ileeṣẹ ọlọpaa si ẹhonu awọn ọlọpaa to n fapa janu ree

Amọṣa, ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria ti sọ pe o ṣeeṣe ki o ri bẹẹ ṣugbọn eyi ki i ṣe lati ọdọ awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa.

Ninu atẹjade kan ti alukoro agba fun ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria, CSP Olumuyiwa Adejọbi fi sita, awọn banki kan ti awọn ọ̀lọpaa kan fi ranṣẹ pe ki wọn san owo ajẹmọnu awọn si lo ni kudiẹkudiẹ yii, kii ṣe latọdọ ọ̀lọpaa.

Ọlọpaa kan pẹlu Ibọn

gbogbo awọn ọlọpaa to kopa ninu eto idibo gomina nipinlẹ Ọṣun ni wọn fi aṣuwọn ifowopamọsi wọn ṣọwọ si ẹka iṣuna ileeṣẹ ọlọpaa nibẹ ni wọn si ti pin owo sinu aṣuwọn ọlọpaa kọọkan...

Amọṣa, ọkan lara awọn banki igbalode kan ti awọn ọ̀lọpaa miran ni ki wọn san owo awọn si lo ni idiwọ imọ ẹrọ nipa sisan owo naa. A si ti gbe igbesẹ lori rẹ, banki ọhun si ti bẹrẹ sisan owo naa lẹyẹ o ṣọka.”

Ọpọ awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ ati ọgba ni wọn kan saara si awọn ọlọpaa Naijiria fun iṣẹ ti wọn ṣe lasiko idibo naa.