Hamed Babayoko: Ẹ wo orílẹẹ́èdè tó pàdánù adarí ìjọba méjì láàrin ọdún kan

Oríṣun àwòrán, Reuters
Olootu orilẹede Ivory Coast, Hamed Babayoko ti papoda ni ileewosan ni orilẹede Germany.
Awọn alaṣẹ to fi idi ọrọ yii lede sọ pe Babayoko papoda ni ẹni ọdun mẹrindinlọgọta leyin aisan jẹjẹrẹ.
Oṣu Keje, Ọdun 2020 ni wọn yan an si ipo lẹyin ti olootu ijọba to wa nipo tẹlẹ, Amadou Gon Coulibaly dede ku iku ojiji.
- Ṣé lóòtọ́ ni Alaafin Ọyọ ti fẹ́ olorì tuntun láti ẹ̀yà Igbo? Ẹ wo ǹkan tí a mọ̀ nípa rẹ̀
- A ò lè kọ ẹbí olóògbé Kashy bí wọn ṣe máa hùwà torí ọmọ wọn papòda àmọ mo mọ̀ pé Barry Jhay... - Ẹbí Sikiru Ayinde Barrister
- Wàwúù!!! Lẹ́yìn ọmọ márun-ùn, wo bí ìyàwó àgbẹ̀ se tún bí ìbaàrùn-ún ní Ogbomoso láì ṣe iṣẹ́ abẹ
- Alaafin bi ibeji l‘ẹẹmeji lọsẹ kansoso
- Bí ilé ẹjọ́ bá pàṣẹ kí Krìstẹ́nì àti Mùsùlùmí máa pe Ọlọ́run ní Allah, kí lẹ ó ṣe?
- Wo ohun mẹ́fà tó yẹ kí o mọ̀ nípa ìbọn AK-47
Aarẹ orilẹede naa, Alassane Quattara ṣe apejuwe Arakunrin Babayoko gẹgẹ bi eniyan nla to ku ipa ribiribi lawujọ.
O fikun wi pe Babayoko jẹ awokọṣe fun awọn ọdọ gẹgẹ bi adari to ṣe e gbojule.
Oṣu Keji, ọdun yii ni wọn gbe Babayoko lọ si orilẹede Faranse lẹyin ti ara le ti ko ya tun buru si ju ti tẹlẹ lọ.
Babayoko to jẹ onimọ nipa eto iroyin tẹlẹ lo darapọ mọ oṣelu to si ko ipa ribiribi ninu ipẹtu si aawọ lasiko ogun abẹle lorilẹede Ivory Coast.
Yato si ipo rẹ gẹgẹ bi Olootu ijọba, Babayoko ni minisita fun eto aabo lorilẹede naa.
Nibayii, Patrick Achi ni olootu ijọba fidiẹ, nigba ti aburo aarẹ , Arakunrin Birahima Quattara yoo di ipo minisita fun eto aabo mu fun igba diẹ.












