Àwọn ọ̀dọ́ dáná sun ààfin Ọba Iree, ọ̀rọ̀ di bóò lọ o yàgò!

Oríṣun àwòrán, adulawonewsng
Rogbodiyan ti bẹ silẹ niluu Iree, ni ijọba ibilẹ Ariwa Boripe, nipinlẹ Osun lẹyin ti awọn janduku kan dana sun awọn ile kan ninu aafin Ọba ilu naa.
Iṣẹlẹ ọhun mu ki awọn ọdọ naa di awọn oju ọna to wọ ilu ọhun.
Iroyin ni eredi ikọlu naa ko ṣẹyin pe inu awọn ọdọ ilu ọhun ko dun si bi awọn agbofinro ṣe fi ṣikun ofin mu oloye Aogun ilu naa, iyẹn Soliu Atoyebi.
Awọn ọdọ naa ṣe ikọlu si aafin Ọba Iree ni nnkan bii aago meje alẹ Ọjọbọ, lasiko ti Ọba Ponle Ademola si ko nile.
Ni ṣe ni awọn oniṣowo to wa ninu ilu ọhun tete ti awọn ileeṣẹ ati ṣọọbu wọn nitori rogbodiyan naa, nigba ti awọn eeyan ilu ọhun si ti ara wọn mọ inu ile wọn.
Akọroyin BBC to wa nipinlẹ Osun fidi iroyin naa mulẹ, amọ gbogbo akitiyan lati kan si alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun, Yemisi Opalola, lati sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun ko so eso rere.
Ọjọ Aje ni gomina ipinlẹ Ademola Adeleke ti kọkọ wọgile iyansipo awọn ori Ade kan nibẹ.
Lara awọn ori ade naa ni Aare ti ilu Ikirun, Akirun ti ilu Ikirun ati Owa ti Igbajo.
Adeleke tun ni ki wọn gbe Aafin awọn ori ade naa ti pa, ki awọn agbofinro si wa nibẹ wamuwamu nitori awọn ti yoo gbiyanju lati da ilu ru nibẹ.
Ṣaaju ni awọn eeyan kan ti kọkọ n fapa janu lẹyin ti gomina ana nipinlẹ ọhun, Gboyega Oyetole kede ọmọba Ponle Ademola gẹgẹ bii Aree ti ilu Iree.
Lẹyin naa ni awọn idile kan ti sọ pe awọn ko faramọ bi ijọba ṣe yan ọmọ ọba naa nitori o fara jọ bii pe ijọba mọọmọ gbe ọkunrin naa le awọn lori ni.












