Tinubu kò bẹ̀rù àti forígbárí pẹ̀lú ẹnikẹ́ni – Femi Fani-Kayode

Tinubu nibi eto ipolongo kan

Oríṣun àwòrán, Bola Ahmed Tinubu

Oludije fun ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu APC lorilẹede Naijiria, Bọla Ahmed Tinubu kii bẹru ati forigbari pẹlu ẹnikẹni ninu tabi oludije ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu yooku eto ifọrọwerọ itagbangba.

Minisita fun irinajo ofurufu lorilẹede Naijiria nigbakan ri, Fẹmi Fani-Kayọde lo sọ ọrọ yii.

Amofin Fani-Kayọde sọ ọrọ yii ninu ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu BBC nibi to ti dahun awọn ibeere nipa eto idibo ọdun 2023 ati bi o ṣe kan awọn oludije lẹgbẹ oṣelu APC.

Lori ọrọ ifọrọwerọ ita gbangba ti awọn eeyan n kun kaakiri bayi pe o dabi ẹni pe oludije ẹgbẹ oṣelu naa n fi ọgbọn sa fun, Fani Kayọde ni ọrọ ko ri bẹẹ rara.

“Ọwọ oludije lọrọ yii wa o, o si tun da lori bi ilana irin ati eto rẹ ba ṣe jẹ. ọpọlọpọ eto lo wa niwaju rẹ. Tinubu ti ṣe ọpọlọpọ eto ipolongo, ipade ijiroro ilu si ilu, o si ti ba awọn eeyan sọrọ lojukoju nibi to ti dahun ibeere lawọn eto naa ju apapọ gbogbo awọn oludije lapapọ.”

Tinubu lẹtọ lati yan ibi ti o ba fẹ lọ tabi ti ko ni lọ -FFK

Tinubu, Aarẹ Buhari atawọn agbaagba ẹgbẹ oṣelu APC

Oríṣun àwòrán, Bola Ahmed Tinubu

O fi kun pe Tinubu lẹtọ lati yan ibi ti o ba fẹ lọ tabi ti ko ni lọ.

“ Ko ni lọ si ibi ti o ba mọ pe awọn eeyan yoo ti lẹdi apo pọ ṣe oun ni ijamba, ṣugbọn yoo wa awọn ibi ti yoo ti lee ba araalu sọrọ.. ohun ti o n ṣe niyi, ti yoo si tun tẹsiwaju lati maa ṣe.

“Boya ti wọn ba pe e si ibi awọn ifọrọwerọ ita gbangba wọnyii ni ọna to ba mu laakaye yoo lee wo o ṣe nitori ohun gangan lo ni ẹtọ ati yan an tabi ko maa yan.

“Ṣugbọn ẹ jẹ ki n sọ nnkankan fun yin, ko si ẹni ti ko le ba figagbaga lori ifọrọwerọ ninu gbogbo wọn, bo jẹ ẹni kan si ẹnikan, iyẹn da mi loju daadaa. Ki wọn bii lere na, ka wa rii.”

‘Peter Obi ko si lẹgbẹ ẹni ti a o maa ba figagbaga...kii ṣe ẹni ti a ri ti ẹ ro rara’

Peter Obi, oludije ẹgbẹ oṣelu Labour

Oríṣun àwòrán, peter obi

Fani-Kayọde tun sọrọ lori fidio kan to n ja ranyinranyin lori ayelujara nibi ti Tinubu ti n tọka si oludije fun ẹgbẹ oṣelu Labour Party, Peter Obi pe “arinfin nla ni ki wọn maa darukọ rẹ”

“Ohun to wu u lati sọ ni. Pupọ awọn nnkan ti Obi funrarẹ ti sọ nipa oludije wa gan to mu ki eeyan pinnu pe ki ni yoo mu migboriyin fun orukọ ẹni bẹẹ bi wọn ba darukọ rẹ layika mii.”

‘Aye wa fun Wike atawọn gomina marun un to wa ni Integrity group bi wọn ba fẹ wa si APC’

Awọn gomina Integrity group

Oríṣun àwòrán, Nyesom Wike

Fani-Kayọde to ti figba kan jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP tun mẹnu le ọrọ lori ipenija to n koju ẹgbẹ oṣelu alatako APC nibi ti awọn gomina marun un ti ya pa labẹ idari Nyesom Wike, gomina ipinlẹ Rivers.

“Lakọkọ naa mo kan sara si wọn fun igboya wọn. Wọn n pe ara wọn ni integrity group bayii, bẹẹni ẹnikẹni to ba lorukọ rere kaabọ si aarin wa

“Mo lero pe wọn ni igboya lati wa darapọ ṣe atilẹyin fun Tinubu nitori pe wọn ko ni ọna miran bayii.

“Mo maa rọ Wike lati tẹsiwaju ohun to n ṣe ki o si duro lori ipiinu rẹ. Ki i ṣe iwa to tọ ni wọn hu si wọn ni aarin ẹgbẹ oṣelu wọn, ohun to si tọ ni wọn n ṣe.”

‘Ẹsun ogun oloro gbigbe ti wọn n fi kan Tinubu ko ba wa lẹru rara’

Tinubu pẹlu Aarẹ Buhari

Oríṣun àwòrán, bola ahmed tinubu

Lori ẹsun gbigbe ogun oloro ti wọn fi n kan oludije fun ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu to n ṣejọba bayii, agbẹnusọ fun ikọ ipolongo Tinubu/Shettima naa sọ pe “Ko tilẹ kan wa nitori pe irọ lasan ni.”

Fẹmi Fani-Kayọde ṣalaye pe “bi awọn eeyan ba fẹ joko lati gba irọ gbọ, ko wa kan awa lati wa joko lọsan ati loru maa pọn iru irọ bẹẹ lewe.

“Ẹsun ti wọn ti gbe kalẹ lati bii ọgbọn ọdun sẹyin, ohun ti ijọba Amẹrika funrarẹ nipasẹ awọn oṣiṣẹ wọn lorilẹede Naijiria ti wa sọ pe ko si igba kankan ti wọn da a lẹjọ lori rẹ, ti wọn tun fi da miliọnu kan dọla pada fun ẹni ti wọn n sọ pe o jẹ agboogun oloro. Eyi ko mu ọpọlọ dani rara.”