Sikirulai Ogundele, alága PDP Ogun: Ibi tí ọ̀rọ̀ dé dúró lórí olùdíje gomina PDP Ogun rèé

Àkọlé fídíò, Sikirulai Ogundele, alága PDP Ogun: ibi tí ọ̀rs dé dúró lórí olùdíje gomina PDP Ogun rèé

Wo ohun to fa awuyewuye lori ẹni ti yoo dije dupo gomina labe asia PDP ni ipinle Ogun.

Ọrọ idibo ipinlẹ Ogun paapaa lati ni oludije ninu ẹgbẹ oṣelu People's Democratic Party n bi ige ati adubi.

Saaju ni wọn ti kọkọ fa ọmọ oye kan kale, iyẹn Adebutu lati isalẹ wa ki ọrọ to bẹyin yọ.

Eyi lo jẹ ki BBC Yoruba kan si alaga ẹgbẹ PDP nipinlẹ Ogun lati mo nkan to n ṣẹlẹ bayii.

Alhaji Sikirulai Ogundele salaye bi ọrọ ṣe ṣelẹ lati ibẹrẹ wa.

Bakan naa lo sọ ipa ti awọn ẹka Jimi Lawal ko ninu iṣẹlẹ naa ati idi ti awọn kan fi kuku gba ile ẹjọ lọ.

Sikirulai Ogundele mẹnuba pataki iwe ofin Naijiria mẹtẹẹta lori yiyan oludije dupo ati ipa ti awon oloye ẹgbẹ PDP Ogun ti ko lori ọrọ naa .

Bayii Ladi Adebutu ni ile ẹjọ jan lontẹ lati dije dupo gomina ipinlẹ Ogun labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP bayii,