Ọjọ́ méjì péré tí Adeleke dé’pò, gbogbo Osun ti dàrú, ẹ̀yin èèyàn wa l’Osun ẹ kú ìrọ́jú o! – APC

Oyetola ati Adeleke

"Kìí ṣe ìfẹ́ àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Osun ni àjọ elétò ìdìbò gbé síta, a ó jẹ́rìi bọ̀ ní Tribunal."

Igun Gomina to kuro lori alefa nipinlẹ Osun ti fesi si gbogbo rogbodiyan to wa nilẹ lori awọn igbesẹ ti Gomina to ṣẹṣẹ dori oye n gbe lẹnu ọjọ diẹ to de ibẹ.

Olugbaninimọran pataki fun Gómìnà ana ni ipinlẹ Osun Gboyega Oyetola lori ọrọ oṣelu, Oluomo Sunday Akere ba lo ba BBC Yoruba sọrọ.

Lori ọrọ ẹjọ to wa laarin Oyetola ati Adeleke lo fi bẹrẹ to si ni “ofin orilẹede Naijiria fun ẹnikẹni ni aṣẹ pe ti idibo ko ba tẹ oludije kan lọrun, o lẹtọ lati lọ sile ẹjọ́.”

Akere ni awọn si nigbẹkẹle pe lagbara Ọlọrun awọn lawọn maa bori nibẹ.

O ṣalaye pe ilẹ ẹjọ ti wọn ti n gbọ ẹjọ oṣelu (Tribunal) ti pa a laṣẹ ati dandan pe ki ajọ eleto idibo ko gbogbo iwe ẹri Ademola Adeleke wa ni Ọjọbọ ọsẹ fun igbẹjọ to kan, “a dẹ mọ wipe wọn fẹ wọn kọ, wọn gbọdọ̀ ko o wa, a dẹ mọ pe lagbara Ọlọrun a o jẹri bọ ni Tribunal.”

Ademola Adeleke

“Adiyẹ ti ba le okun l’Osun, ara o rọ okun ara o rọ adiyẹ mọ!”

Ademola Aeleke

Oríṣun àwòrán, Ademola Adeleke/Twitter

“Láti Ọjọ Aiku ti wọn ti burawọle fun Adeleke ni ẹgbẹ alaburada ti ko rogbodiyan ba ilu, wọn si ni adiyẹ ba l’okun, ara o r’okun, ara o rọ adiyẹ mọ ni.”

Akere sọ pe ohun ti awọn fẹ rọ awọn ọmọ́ ẹgbẹ awọn ni pe ki wọn ma foya ki wọn fọkan balẹ toripe gbogbo awọn lawọn yoo ko ara wọn lọ ile ẹjọ ni Ọjọbọ lati feti si bi igbẹjọ naa ṣe n lọ.

Bakan naa ni wọn ke si awọn agbofinro ki wọn ma kawọ gbera ki wọn ṣiṣẹ wọn tori gbogbo awọn lawọ́n jọ ni ilu. Si eyi o ni awọn n rọ awọ́n agbofinro ki wọn ṣe iṣẹ wọn tori awọn ko ṣe nkankan.

Ṣe APC lo sanwo fawọn tọọ́gi lati ṣekọlu sira wọn?

Gboyega Oyetola

Oríṣun àwòrán, OTHERS

“A wa nijọba fun ọdun mejila, ilu o daru, ki wa ni tiwa nitori wọn n bura fun eeyan ti a mọ pe kii ṣe ẹtọ wọn.”

O ni awọn o dẹ ni gba ki alafo wa ninu iṣejọba torinaa aṣẹ wa lọwọ gomina lati yan ẹni to ba wu u.

Ọgbẹni ṣalaye pe kii ṣe ẹgbẹ APC lo sanwo fun janduku, ṣe a fẹ maa ya “poster ara wa ni”.

Torinaa, o ni ki wọn pe awọn ọmọ wọn ki wọn so ewe agbejẹ mọwọ toripe ilu Osun kii ṣe ilu onijagidijagan, ilu awọn ọmọwe ni to si ni ki wọn ma da a ru fun awọn.

Lori ọrọ awọn oṣiṣẹ ti iroyin ni Adeleke da duro bo ṣe de ori itẹ

“Ohun ti ofin sọ ni wipe ọjọ Kẹrindinlogun oṣu Kọkanla ni ago mejila oru ni gomina to ba n kogba wọle lọ to le pari iṣẹ, a o dẹ ni gba ki alafo wa ninu eto iṣejọba torinaa gomina ni aṣẹ lati yan ẹni to ba wu u.”

Awọn Ọba ilu wa nkọ?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

"O ṣẹlẹ lasiko Bisi Akande ati Olagunsoye Oyinlola".

Akere ni awọn araalu lo maa n yan Ọba, awọn afọbajẹ lo ni wọn maa n ṣe eyi kii ṣe gomina.

Bo tilẹ jẹ pe aṣoju APC yii sọ pe awọn naa ti n wo awọn aṣiṣe wọn tori pe ẹni to n gbẹnusọ fun Adeleke naa sọ lori rẹdio laarọ pe awọn kan yan igbimọ ti yoo wo ilana bi wọn yoo ṣe jẹ Ọba nii, kii ṣe pe awọn rọ Ọba loye.

O ni awọn Ọba ti wọn sọrọ wọn yii, awọn Ọba tawọn araalu n fẹ ni wọn.

Bakan naa, o ni kii ṣe awọn lo kọkọ maa jẹ Ọba akọ́kọ́. “Nigba ti gomina to wa lori oye tẹlẹ ri ni 2003, Oloye Bisi Akande yan Ọba fun ilu Illa nigba to ku ọjọ mẹrin ti yoo kuro lori oye.”.

O ṣalaye pe nigba ti Ọmọba Olagunsoye Oyinlola dẹ de ibẹ, ko sọpe tori bẹẹ pe oun yọ Ọba yii kuro.

“Awọn to fi sọkan pe awọn gba eku ida Osun lọwọ lọwọ bayii, wọn o ni ohun ti oloyinbo n pe ni “experience”, wọn kan n tẹ ilẹ baṣubaṣu ni, ṣugbọn a mọ wipe fun igba diẹ ni a o dẹ ni gba wọn laye ki wọn ba ilẹ jẹ ki wọn to kangara wọn kuro.

O ṣalaye pe Oloye Eesa ilu Ikirun to ni Ọna oṣelu ni wọn lo ti wọn fi gbe Ọba tipatipa le awọn lori, o ni irọ patapata ni toripe oun nikan lo dibo tako nnkan tawọn afobajẹ marun to ku dibo fun.

Bakan naa lo ni awọn ọdọ ilu o jo aafin kankan to si ni Ọba ilu Ikirun wa laafin rẹ lọwọlọwọ.

“Pẹlu gbogbo bi ilu ṣe n da ilu ru, ẹ ba wa ki awọn eeyan wa l’Osun pe wọn ku irọju o!”

Kí ni PDP Osun sọ si gbogbo ọ̀rọ̀ APC yìí?

Nigba ti a pada ribi kan si ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party ni Osun, ọrọ kun ilẹ.

Agbẹnusọ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party ni ipinlẹ Osun sọ fun BBC Yoruba pe nigba ti eeyan kan ba ṣẹṣẹ de ijọba oriṣiriṣi nnkan ni yoo maa ṣẹlẹ.

"Awọn mii ti inu wọn a dun ladunju, awọn mii ti yoo maa huwa, oro too dami lemi naa yoo da ọ".

O ṣalaye pe idarudapọ diẹ diẹ to wa lọjọ keji ọjọ ti wọn bura fun Gomina Adeleke jẹ bii ayasi awọn nnkan to ti wa nilẹ ki ijọba to kogba wọle to lọ ni.

O ni ko si nii ṣe pẹlu araalu rara amọ ilana iṣejọba laarin ẹgbẹ awọn awakọ ni ti wọn jẹ ololufẹ ati Gboyega Oyetola ati ADemola Adeleke to si ti kilọ fun wọn pe ki wọn lọ so ewe agbejẹ mọwọ tabi ki wọn foju wina ofin.

Torinaa, "ẹgbẹ oṣelu PDP ko da ipinlẹ Osun ru rara tori awa kii ṣe ẹgbẹ onijagidijagan".

Gbogbo isọri akori to wa ninu iroyin yii ni PDP fesi sii, a o si mu afikun rẹ wa fun un yin laipẹ, amọ ẹ ka eyi na.