Oyetola: Bílíọ̀nù mẹ́rìnlá náírà ni mo fi kalẹ̀ fún ìjọba tuntun

Gómìnà Gboyega Oyetola

Oríṣun àwòrán, Others

    • Author, Faoziyah Saanu-Olomoda
    • Role, Broadcast Journalist

Gómìnà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kúrò nípò ní ìpínlẹ̀ Osun, Gboyega Oyetola ní bílíọ̀nù mẹ́rìnlá ni òun fi kalẹ̀ sí àpò ìjọba ìpínlẹ̀ náà fún ìjọba tuntun ti Ademola Adeleke.

Oyetola sọ èyí nínú ọ̀rọ̀ ìdágbére láti gbé ìjọba ìpínlẹ̀ Osun kalẹ̀ fún gómìnà Ademola Adeleke tí àjọ elétò ìdìbò Nàìjíríà, INEC kéde pé òun ló gbégbá orókè níbi ètò ìdìbò tó wáyé ní ọjọ́ Kẹrìnlá, oṣù Keje, ọdún 2022.

Ọ̀rọ̀ ìdágbére náà tí agbẹnusọ Oyetola, Ismail Omipidan fi léde lọ́jọ́ Àìkú ní ìjọba Oyetola san àjẹ́lẹ̀ bílíọ̀nù mẹ́tàdínlọ́gọ̀rún-ún nínú gbèsè tí ìjọba tó gbésẹ̀ jẹ kalẹ̀ dé òun.

Bákan náà ni gómìnà àná náà tún fi kun pé ìjọba òun kò yá kọ́bọ̀ láti fi gbe ètò ọrọ̀ ajé ìpínlẹ̀ Osun lẹ́sẹ̀ lásìkò tí òun wà nípò gẹ́gẹ́ bí gómìnà.

Oyetola tún ní yàtọ̀ sí bílíọ̀nù mẹ́rìnlá náírà tí àwọn fi kalẹ̀ sápò ìjọba, bílíọ̀nù mẹ́jọ náírà mìíràn yóò tún wọ àpò ìjọba láàárín oṣù kejìlá sí oṣù kìíní ọdún tó ń bọ̀.

Ó ṣàlàyé pé bílíọ̀nù mẹ́jọ náà jẹ́ owó tí àwọn pa wọlé lábẹ́nú àti owó ètò kan tí wọ́n pé ni States Fiscal Transparecy, Accountability and Sustainable (SFTAS) tó jẹ́ ètò ìjọba.

Gómìnà àná náà tẹ̀síwájú pé ìpínlẹ̀ Osun náà jẹ àǹfàní bílíọ̀nù mẹ́ta náírà tí ìjọba àpapọ̀ fún àwọn ìpínlẹ̀ fún oṣù mẹ́fà láti lè bọ́ lọ́wọ́ ìpénìjà tí yíyọ nínú àbá ìsúná kó bá wọn àti sísan owó oṣù àwọn òṣìṣẹ́.

Bẹ́ẹ̀ náà ló tún sọ pé iṣẹ́ takuntakun tí ìjọba òun ṣe yóò mú kí wọ́n rí mílíọ̀nù méjìlélàádọ́rin dọ́là owó ìrànwọ́ ìjọba àpapọ̀, NG-CARES gbà láìpẹ́.