Ìléeṣẹ́ tó ń rí sí ìwé ìrìnnà ní Naijiria ti gbà láti máa ṣí ní Sátidé

Aworan

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ileeṣẹ to n risi eto iwe irina lorilẹede Naijiria, NIS ti fun awọn ileeṣẹ wọn ni aṣẹ lati maa ṣi ni Ọjọ Satide.

Adari ileeṣẹ Nigeria Immigration Service(NIS) lo fi aṣẹ naa lede ninu atẹjade ti wọn fi lede.

Ninu atẹjade naa ni wọn ti fi lede pe igbeṣẹ ọhun yoo fun awọn eniyan ni anfaai lati gba iwe irinna wọn ni asiko.

‘’Ajakalẹ aarun Coronavirus lo mu ifasẹyin de ba gbigba iwe irinna ni Naijiria’’

‘’Igbiyanju wa ni pe ki irọrun wa fun awọn eniyan lati gba iwe irinna wọn to ti wa ni ikawọ wa lati igba to ti pẹ.

‘’A ri pe idiwọ wa lati igba ti aarun Coronavirus ti gbode kan, eleyii to fa iṣẹde nigba naa lọhun, ti a ko si ri aye ṣiṣẹ, eleyii mu idiwọ ba awọn eniyan to yẹ ki wọn rin irinajo ti wọn ko si ri iwẹ irinna wọn gba.’’

‘’Idaju wa pe ti awọn oṣiṣẹ wa ba bẹrẹ si ni ṣiṣẹ ni Satide yoo mu irọrun gba gbigba iwe irinna awọn araalu.’’

Bakan naa ni wọn kede pe awọn ti gbe awọn adari ẹka ileeṣẹ wọn meji ni ipinlẹ Ondo ati Ekiti ki iṣẹ le tẹsiwaju ju ti atẹyinwa lọ.