Irọ́ ni ọkùnrin tó ní àwọn ajínigbé gbé òun l’Ekoo ń pa - Ọlọ́pàá

Ọkùnrin náà àti Agbẹnusọ Ọlọ́pàá Eko, Benjamin Hundeyin

Oríṣun àwòrán, Twitter

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko ti fèsì sí fídíò kan tí ọkùnrin kan fi síta láti ṣàlàyé bí àwọn ajínigbé ṣe ko mọ́ àwọn ènìyàn mìíràn ní agbègbè Lekki sí Ikoyi.

Agbẹnusọ ọlọ́pàá Eko, Benjamin Hundeyin sọ pé irọ́ ni ọkùnrin náà ń pa.

Hundeyin ní gbogbo ìwádìí àwọn láti ìgbà tí ọkùnrin rin ti fi fídíò náà léde tó si ti gba orí ayélujára fihàn pé irọ́ tó jìnà sí òótọ́ ni ohun tí ọkùnrin náà sọ nínú fídíò ọ̀hún.

Ó ní láti ìgbà tí fídíò náà ti gba ìgboro ni àwọn ti kán lu ìwádìí láti mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ lórí gbogbo ẹ̀sùn tí ọkùnrin náà fi kàn.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Kí ni ohun tí ọkùnrin náà sọ?

Nínú fídíò náà ni ọkùnrin yìí ti ṣàlàyé gbogbo ohun tí ojú rẹ̀ rí lọ́wọ́ àwọn afurasí gẹ́gẹ́ bí ajínigbé kan tí òun wọ ọkọ̀ wọn.

Ó ní agbègbè Lekki sí Ikoyi ni òun ti wọ ọkọ̀ tó ń lọ sí Iyana-Oworo ní nǹkan bí i aago méje sí mẹ́jọ alẹ́.

Ọkùnrin ọ̀hún tí gbogbo ojú rẹ̀ wú tí ẹ̀jẹ̀ sì wà ní gbogbo imu rẹ̀ mọ́ ibi ẹnu rẹ̀ nínú fídíò náà ní nígbà tó ṣe díẹ̀ tí mótọ̀ àwọn ti wà ní orí ìrìn ni òun ṣàdédé bẹ̀rẹ̀ sí ní gbọ́ òórùn afẹ́fẹ́ gáàsì.

Ó fi kun pé gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ti gbé pẹ̀lú àwọn sójà rí, òun ti mọ̀ wí pé òórùn gáàsì náà máa ń mú oorun kun ènìyàn ni òun bá tutọ́ sínú áńkì kékeré tó wà lọ́wọ́ òun tí òun sì fi bomú.

“Kò pẹ́ ni gbogbo àwọn tó wà nínú ọkọ̀ sùn lọ fọnfọn àyàfi àwọn tó jẹ́ ajínigbé ọ̀hún tí wọ́n ti lo ìbòmúbonu àti òun.”

Ó nígbà tí wọ́n rii pé òun kò sùn ni èyí tó dàbí ọ̀gá wọn bèèrè lọ́wọ́ òun wí pé kí ló dé tí òun kò sùn ni òun bá bẹ̀rẹ̀ sí ní bẹ̀ wọ́n pé kí wọ́n jọ̀wọ́ tú òun sílẹ̀.

“Wọn kò gbọ́ gbogbo ẹ̀bẹ̀ mi, mo ní kí wọ́n gba fóònù mi tó lé ni mílíọ̀nù kan náírà, káàdì ATM mi, ẹ̀gbà ọrùn tó jẹ́ góòlù tí owó rẹ̀ wọ mílíọ̀nù náírà àmọ́ wọ́n kọ̀ jálẹ̀.”

“Wọ́n ní àwọn yóò pamí ni tí àwọn bá ti rí ibi tó dára láti gbẹ̀mí lọ́rùn mi ni.”

Ó ní kò pẹ́ tí òun bẹ̀rẹ̀ sí ní pariwo ni wọ́n yà kúrò lójú títì wọ abẹ́ bírìjì kan tó já sí ọ̀nà Adeniji Adele, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní lu òun.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọkùnrin náà tẹ̀síwájú pé nígbà tí wọ́n dé abẹ bírìjì náà ni àwọn afurasí ajínigbé náà yọ ọ̀bẹ àti awọn nǹkan ìjà olóró mìíràn láti fi pa òun.

Àmọ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ilẹ̀ Adúláwọ̀ tí òun jẹ́, àwọn àjẹsára tó wà lára òun kò jẹ́ kí ọ̀bẹ àti nǹkan tí wọ́n fẹ́ fi ṣe òun ní jàmbá wọlé sí òun lára.

“Nígbà náà ni wọ́n gbèrò láti fi nǹkan fọ́ orí òun, tí àwọn kan nínú wọn sì fi bàtà tí wọ́n wọ̀ gbá ohun lójú àti orí kí òun le kú.”

“Báàgì tó wà nílẹ̀ ni mo gbé tí mo sì mú ọ̀bẹ tó wà níbẹ̀ láti máa jù ú fìrìfìrì tó sì díẹ̀ nínú wọn.”

“Ìgbà yìí ni ọ̀gá wọn sọ wí pé kí wọ́n fi mí sílẹ̀ pé ṣebí àwọn ní àwọn tó ti sùn lọ tó wà nínú ọkọ̀ kí àwọn máa kó àwọn wọ̀nyẹn.”

Ó ní bí òun ṣe móríbọ́ lọ́wọ́ wọn nìyẹn.

Nínú fídíò ọ̀hún ló ti wá ń ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Eko láti wà ní tojútìyẹ́ pé àwọn oníṣẹ́ ibi ti wà káàkiri ìpínlẹ̀ Eko pàápàá ní àwọn agbègbè tó jẹ́ àdúgbo olówó.

Bẹ́ẹ̀ náà ló tún ní àwọn tí wọ́n ṣe iṣẹ́ láabi náà fun òun ló jẹ́ ara òkè ọya ṣùgbọ́n BBC kò le ìdí èyí múlẹ̀.

Àmọ́ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní irọ́ ni gbogbo ohun tí ọkùnrin náà sọ pé kí àwọn ènìyàn má bẹ̀rù bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ṣì ń tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìwádìí àwọn.

Ọ̀rọ̀ ààbò ní Nàìjíríà ti di ohun ìbẹ̀rẹ̀ pàápàá ní àwọn agbègbè kan.

Ní bí i ọ̀sẹ̀ mélòó sẹ́yìn ni ìròyin gbòde pé àwọn ajínigbé ń da àwọn ènìyàn lọ́nà ní òpópónà márọsẹ̀ Eko sí Ibadan.