Wo ìgò tó ní akọsílẹ̀ tó ti pé ọdún 135 nínú rẹ̀ tí wọ́n ṣàwárí lábẹ́ ilẹ̀ ilé kan

Iwe inu igo

Oniṣẹ ọna ile kan ti ri igo kan ti iwe akọsilẹ ti ọjọ ori rẹ to aadoje ọdun wa ninu rẹ ni ile kan nilu Edinburgh.

Ọgbẹni Alan ẹni aadọta ọdun ri akọsilẹ naa nigba to ṣi ilẹ ile naani ọgangan ibi ti wọn fi igo ọtí whisky naa si.

Ere tete lo sa lọ si isalẹ lati fi ohun to ri to onile naa leti lagbegbe Morningside.

Elilidh Srimpson ni lati fọ igo naa lati ka akọsilẹ to wa ninu iwe inu rẹ naa. O ni inu awọn ọmọ oun mejeeji lo dun si ohun ti wọn ri naa.

Ọgbẹni Allan fi to BBC Scotland leti pe iyalenu nla lo jẹ fun oun.

“Ẹsẹ bata mẹta si marundinlogun ni iwọn yara naa, mo si ti gbẹ ilẹ to wa layika igo naa lai mọ pe o wa nibẹ.”

Ọgbẹni Allan ni oun mu u tọ iya onile naa lọ nisalẹ. O ni abẹ ilẹ yara ọmọ ọdọ ni oun ti ri i.

Arabinrin Eilidh Stimpson ati ọkọ rẹ lo n gbe ninu ile naa. O si duro titi ti awọn ọmọ rẹ ti wọn jẹ odun mẹjọ ati mẹwaa oada de lati ile ẹkọ ki wọn to fọ igo naa lati yọ iwe inu rẹ.

Arabinrin naa ṣalaye fun BBC Scotland pe: “ Nigba ti mo lọ gbe wọn ni ile ẹkọ mo sọ fun wọn pe mo ni nnkan iyanu kan lati so fun won. Awọn ọmọ mi ni ṣe awọn fẹ fi hot dog mu tii ni?

Mo sọ fún wọn pe a ri igo adayeba kan ni ile wọn inu wọn si dun gidi pe boya ohun alumọni ni yoo jẹ.”

Iwe akosi inu igo

Oṣiṣẹ meji to jẹ ọkunrin lo buwọlu iwe naa ti wọn si kọọ sinu rẹ pe: “James Ritchie ati John Grieve lo ṣe ilẹ ile yii, ṣugbọn wọn ko mu ọti Whisky yii. Ọjọ kẹfa oṣu kẹwaa ọdun 1887.”

Arabinrin Stempson ni, “O dun mi pe mo ni lati fọ igo to ti pe ọdun marundinlogoje yii.”

Lẹyin awari ohun meremere yii, ọrẹ rẹ kan ti ri orukọ awọn mejeeji ninu iwe onka araalu ti ọdun 1881. Nibi ti wọn ti rii pe agbegbe Newi gton nitosi ibi ti wọn ti ri igo naa ni awọn ọkunrin mejeji naa n gbe nigba naa.

Arabinrin onile naa ti sọ pe awọn yoo ṣe igo tuntun pelu akọsilẹ tu tun ati ti atijọ yii sinu rẹ awọn yoo si da a pada si inu iho ti wọn ti wu u jade.