Orí kó ọmọ odún márùn ún tí ejò gbé hánu yọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ori ti kọ ọmọ ọdun marun un kan yọ lọwọ ejo to ṣakọlu si leti adagun odo ‘swimming pool’ ile wọn niluu Australia.
Baba ọmọ naa sọ fun awọn akọroyin pe ṣe ni Beau Blake n luwẹ ninu adagun omi naa ki ejo ọhun, ti iwọn rẹ to iwọn bata mẹta to kọlu.
Iroyin ni ejo naa ti lọ mọ ọmọ naa ki baba-baba rẹ to wọ oun ati ejo naa jade ninu adagun omi ọhun, to si gba ọmọ naa lọwọ rẹ.
Bo tilẹ jẹ pe Beau farapa, amọ ifarapa naa ko pọ ju bo ṣe yẹ lọ.
Baba rẹ ṣalaye fun ileeṣẹ iroyin redio 3AW niluu Melbourne pe awọn nu ẹjẹ ara ọmọ naa, wọn si sọ fun pe ko si iku loju rẹ nitori ejo to bu ṣan ki ṣe ejo oloro.
Baba rẹ naa ni awọn yoo maa bojuto egbo ọhun, awọn yoo si s e itọju rẹ
O ni bo tilẹ jẹ pe ọmọ naa moribọ, iṣẹlẹ ọhun jẹ eyii to ja awọn laya gidi.
Bi ikọlu naa ṣe waye
Nigba to n ṣalaye bi iṣẹlẹ na ṣe waye, baba rẹ ọhun ni “Ọmọ mi n rin lẹba eti adagun omi naa… mo gbagbọ pe ṣe ni ejo naa n duro de ẹni ti yoo bu ṣan ki Beau to de ibẹ.”
“Mo ri nnkan dudu kan to jade ninu igbo, amọ ki wọn to de isalẹ adagun omi naa ejo ọhun ti lọ mọ Beau lẹsẹ.”
Lọwọ kan naa ni baba-baba ọmọ ọhun, Allan, bẹ sinu omi naa, to si doola ọmọ-ọmọ rẹ.
O sọ fun awọn akọroyin lori redio pe kii ṣe ohun babara pe awọn n ri ejo layika awọn nitori bo ṣe n ri nilẹ Australia niyẹn.












