Obìnrin kan pe Trump ní ẹjọ́ lórí ìfipá bánilòpọ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images/Reuters
Onkọwe kan, E Jean Carroll, ti pe aarẹ America nigba kan, Donald Trump, ni ẹjọ fun ẹsun ifipabanilopọ.
Arabinrin Carroll, to ti pe ẹni ọdun mejidinlọgọrin bayii sọ pe Trump fi ipa ba oun lopọ ni ọdun 1990.
Carroll wa lara awọn eeyan to kọkọ̀ pe ẹjọ, labẹ ofin tuntun, Adult Survivors Act, to fun awọn agbalagba to ti la ifipabanilopọ kọja, lati pe ẹjọ ni ipinlẹ New York.
Ọjọbọ, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kọkanla, ni ofin naa bẹrẹ iṣẹ.
Ofin naa fi aaye ọdun kan silẹ fun awọn eeyan naa lati pe ẹjọ, ni ipinlẹ New York lori awọn iṣẹlẹ ifipabanilopọ to waye nigba ti wọn ti le ni ọdun mejidinlogun, to si ti kọja asiko ti ofin fi aaye gba pe ki wọn pe ẹjọ le lori.
Aarẹ tẹlẹ ọhun sọ pe oun ko jẹbi.
Arabinrin Carroll sọ pe ile igbọnsẹ ile itaja nla kan ni iṣẹlẹ naa ti waye ni ọdun mẹtadinlọgbọn sẹyin.
Bakan na lo tun ti pe Aarẹ Trump lẹjọ fun ibanilorukọ jẹ, lẹyin ti Trump fi ẹsun irọ pipa kan-an nigba to kọkọ sọrọ nipa ifipabanilopọ naa ni gbangba lọdun 2019.
Ọgbẹni Trump sọ pe arosọ lasan ni awọn ẹsun naa.
Ọjọ kẹfa, oṣu Keji, ọdun 2023 ni igbẹjọ yoo waye lori eyi.
Ninu atẹjade kan, agbẹjọro fun Arabinrin Carroll, Roberta Kaplan, sọ pe ẹjọ ti awọn ṣẹṣẹ pe ni Ọjọbọ, jẹ ọna lati mu ki Trump jiya fun ifipabanilpọ naa.
Ṣugbọn ṣa, agbẹjọro kan fun Trump, Alina Habba, sọ fun awọn akọroyin nilẹ America pe ẹjọ ti Carroll pe jẹ aṣilo anfaani ti ofin tuntun fun awọn to ti koju ifipabanilopọ ri.
O ni igbesẹ rẹ naa ṣeeṣe ko mu ki wọn o fi ọwọ yẹpẹrẹ mu awọn eeyan ti isẹlẹ ṣẹlẹ si ni tootọ.
Awọn eeyan kan naa ti n mura lati pe ẹjọ tako awọn to fi ipa ba wọn lopọ.
Lara awọn ipẹjọ ti eto ti n lọ lori rẹ ni ti Robert Hadden, dokita onimọ iṣegun oyinbo kan to n tọju awọn obinrin. Ogunlọgọ awọn alaisan to ti tọju ni gbogbo ileewosan to ti ṣiṣẹ ni New York, lo fi ẹsun kan pe o fi ipa ba wọn lopọ.












