Bí obìnrin kan ṣe lu ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ ọmọ ọdún mọ́kànlá pa ní ìpínlẹ̀ Plateau

Kid

Oríṣun àwòrán, HUMAN RIGHTS COMMISSION PLATEAU STATE

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Plateau ti bẹrẹ iwadii lori bi obinrin kan ṣe lu ọmọ ọdọ rẹ to jẹ ọmọ ọdun mọkanla niluu bara, ti ọmọde naa si farapa yanayana, eyi to yọri si iku rẹ.

Ọrọ naa lu jade lẹyin ti ẹleyinju aanu kan, Comfort Moses, ri ọmọde naa lẹgbẹ ile rẹ, to si gbe e lọ sile iwosan fun itọju.

Obinrin naa ṣalaye fun BBC pe “ko le sọrọ, bẹẹ si ni ko le rin, mo wa gbe e kuro nibi to farapamọ si wa sinu ile mi, nibẹ lo ti sọ fun mi pe Margaret ni orukọ oun.”

“Mo gbiyanju lati fun un ni burẹdi ati tea, lẹyin naa ni ọkọ mi bere lọwọ mi pe kini a maa ṣe si ọrọ rẹ, mo si fesi pe ko kesi awọn ọlọpaa.”

 “Asiko ti mo sọ fun un pe a maa pe awọn ọlọpaa lo to jẹwọ fun mi pe egbo wa ni idi oun, ati pe ni gbogbo igba ti obinrin ti oun n gbe lọdọ rẹ ba fun oun niṣe ṣe, ti oun ko si lee ṣe iṣẹ naa lo maa n din dundu iya fun oun.”

Comfort Moses ṣalaye siwaju si pe nigba ti ọkọ oun n gbiyanju lati gbe ọmọ naa lọ si agọ ọlọpaa lo sọ pe oun ko ni le joko nitori egbo to wa nidi oun.

O ni “Egbo kekere kan lasan ni mo kọkọ pe, mo ṣaa sọ fun ọkọ mi ko maa gbe lọ si agọ ọlọpaa, lati ibẹ lọ ni wọn ti gbe lọ sile iwosan kekere kan, amọ ile iwosan naa pe wa pe ọwọ awọn ko ka egbo naa ni a fi gbe lọ si ileewosan fasiti ilu Jos.”

“Ile iwosan naa lo ku si lọjọ Aje, ọjọ kẹrinla, oṣu Kọkanla, ọdun 2022 yii.”

“Gẹgẹ bii obinrin, iku ọmọ naa dun mi pupọ mo si fẹ ki ijọba ṣe gbogbo ohun to yẹ lati dẹkun irufẹ iwa bayii lawujọ wa.”

Margaret ni oloogbe naa sọ fun oun pe nnkan bii ọdun kan loun ti n gbe pẹlu obinrin naa to jẹ ọga rẹ.

 ‘Aṣiṣe ni, iku ọmọ naa dun mi pupọ’

Ọga oloogbe naa to jẹ afurasi, arabinrin Nnaemeka Nwachukwua ti sọ tẹnu rẹ lori iṣẹlẹ naa ati eredi to ṣe maa n naa oloogbe ọhun ni gbogbo igba.

Afurasi naa sọ fun awọn akọroyin pe lootọ ni oun maa na oloogbe naa amọ eredi igbesẹ oun ko ṣẹyin bo ṣe maa n fi oju ara ara rẹ ṣere.

O ni “Ọkan lara awọn ọrẹ mi lo ṣamọna bi wọn ṣe mu ọmọ naa wa fun lati ipinlẹ Kebbi.

“Ọrẹ mi naa sọ fun mi pe iya n jẹ wọn nibi ti wọn wa, wọn si nilo iranlọwọ, bo tilẹ jẹ mi o ba awọn obi rẹ pade, mo ti ba wọn sọrọ lori ẹrọ ilewọ ri.”

Nwachukwua ni oun maa n fi ẹjọ ọmọ naa sun awọn obi rẹ amọ wọn ni ki oun ma da pada sọdọ awọn, ati pe wọn fun oun laṣẹ lati fi ọwọ lile mu gẹgẹ bii oun ṣe le ṣe si ọmọ inu ara oun.

O ni “Gbogbo igba ti mo ba ri to n fi oju ara rẹ ṣere ni mo maa n na.”

Afurasi naa ni bo tilẹ jẹ pe lootọ ni oun maa n na oloogbe ọhun, aṣiṣe ni nina to yọri si iku rẹ jẹ.

O ṣalaye pe “Lọjọ kan, mo n na a lẹyin to ṣe aṣemaṣe kan, amọ bi mo ṣe n na lo n sun sẹyin lai mọ pe mo gbe omi gbigbona kan silẹ ninu abọ, bo ṣe n gbiyanju lati sa fun mi lo ṣeṣi subu sinu omi gbigbona ọhun, ti gbogbo idi rẹ si bo.”

Ẹwẹ, ajọ ajafẹtọ ọmọniyan, Human Rights Commission, ti sọ fun BBC pe kii ṣe igba akọkọ ti irufẹ iṣẹlẹ bayii yoo waye ni ipinlẹ naa ree.

Ileeṣẹ ọlọpaa si ti sọ pe obinrin naa yoo foju bale ẹjọ laipẹ, ko si ni lọ lai jiya to tọ labẹ ofin to ba jẹbi ọrọ ọhun.