Àwọn mọ̀lẹ́bí Sammie Okposo sọ̀rọ̀ lórí ikú rẹ̀

Sammie Okposo

Oríṣun àwòrán, OTHERS

"Pẹlu ọkan wuwo ṣugbọn itẹriba fun Ọlọrun ni mo fi kede ipapoda ọkọ wa, baba wa, ẹgbọn wa, aburo wa, iranṣẹ Ọlọrun, Sammie Okposo."

Eyi wa lara ọrọ to jẹ jade ninu ikede ti ọgbẹni Hector Okposo fi sita lorukọ mọlẹbi Sammie Okposo.

Awọn mọlẹbi gbajugbaja olorin ẹmi naa, Sammie Okposo lo fi ọrọ lede lori iku rẹ.

Ninu atẹjade ti ẹbi naa fi lede ni wọn ti ṣalaye pe lootọ ni gbajugbaja olorin ẹmi naa ti dagbere fun aye ti wọ́ si n daro.

Wọn ni Ọjọ karundinlọgbọn, osu kọkanla, ọdun 2022 lo ki aye pe o digba ose.

Bio tilẹ jẹpe wọn ko sọ ẹkunrẹrẹ nipa iku rẹ, wọn ṣe idaro rẹ pe ẹni ire lọ.

Bakan naa ni wọn ni idaniloju wa fun wọn pe oun sinmi ni ookan aye Jesu, nibi ti yoo ti maa kọrin pẹlu awọn angẹli.

Wọn wa ni awọn yoo fi ẹkunrẹrẹ nipa bi eto isinku rẹ yoo ṣe lọ sita to ba to akoko.

Awọn ọmọ Naijiria ṣe idaro Sammie Okposo

Bio tilẹ jẹpe awọn mọlẹbi beere pe ki wọn jẹ ki awọn ṣe idaro ni kọnkọ, ọpọlọpọ ọmọ Naijiria lo n ṣedaro rẹ lori ẹrọ ayelujara.

Ninu atẹjade awọn mọlẹbi ni wọn ti ni '' wọn rọ awọn eniyan lati fi wọn silẹ ni saa yii lati ṣedaro ni ikọkọ.''

Skip Instagram post, 1
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 1

Ibanujẹ ọkan ni iroyin iku naa jẹ fun ọpọlọpọ awọn olorin ẹmi ati ololufẹ rẹ ni Naijiria ati kaakiri agbaye.

Lara awọn ọmọ Naijiria to kan sedaro rẹ ni adẹrinpoṣonu, Helen Paul ati gbajugbaja oṣere, Richard Mofe Damijo to fi mọ awọn miran.

Skip Instagram post, 2
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 2

Skip Instagram post, 3
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 3

Amọn miran ti wọn tun ṣe idaro rẹ loju opo ikansiraẹni wọn ni Dele Momodu to se apejuwe iku rẹ gẹgẹ bi eleyii to ba oun ninu jẹ julọ.

Bakan naa ni adẹrinpoṣonu Arole naa ṣedaro rẹ pe ẹni ire ti lọ.

Skip Instagram post, 4
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 4

Skip Instagram post, 5
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 5

Nǹkan táa mọ̀ nípa ikú Sammie Okposo tó kọ "Wellu wellu" rèé

Sammie Okposo

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM

Ní òwùrọ́ ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kẹẹ̀dọ́gbọ̀n oṣù Kọkànlá ọdún 2022 ni ìròyìn gba orí ayélujára pé gbajúgbajà olórin ẹ̀mí Sammie Okposo ti jáde láyé.

Gẹ́gẹ́ bí ohun tí alákòso Sammie Okposo tó wà ní United Kingdom sọ fún BBC, ó ní nǹkan bíi aago mẹ́rin ìdájí yìí ni Sammie Okoso ṣà dédé ṣubú lulẹ̀ tó sì gba ibẹ̀ dágbere fáyé.

Ohun tó ṣokùnfà ikú rẹ̀ gan kò ì tíì hàn sí wa ṣùgbọ́n alákòso rẹ̀ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ní Sammie Okposo dákẹ́ sí.

Ta ni Sammie Okposo?

Ní ogúnjọ́, oṣù Karùn-ún ọdún 1971 ní wọ́n bí Sammie Okposo sáyé, èyí túmọ̀ sí pé ọmọ ọdún mọ́kànlélàádọ́ta ni tó fi jádse láyé.

Ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Delta lẹ́kùn ààrin gbùgun orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni.

Gbajúgbajà olórin ẹ̀mí tó ti kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ orin ni Sammie Okposo jẹ́.

Ní ọdún 1995 ló bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ orin kíkọ nígbà tó máa ń kọ orin fún àwọn eléré fíìmù láti lo sí eré wọn gẹ́gẹ́ bí ilé iṣẹ́ ìròyìn kan Believers Portal ṣe sọ.

Lára àwọn orin rẹ̀ tó gbajúmọ̀ ni Wellu-Wellu èyí tó ṣe ní ọdún 2000.

Ó ti gba àmí ẹ̀yẹ lọ́kan-ò-jọ̀kan ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti lókè òkun.

Ní ọdún 2004 ní aṣojú ilẹ̀ Amẹ́ríkà sí Nàìjíríà pe Sammie Okposo láti wá kọrin níbi ayajọ Martin Luther King àti ayẹyẹ ayajọ òmìnira wọn lọ́jọ́ Kẹrin oṣù Keje.

Ní ọdún 2010 ló ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú aya rẹ̀, Ozioma.

Iwa wo ni Sammie Okposo hu, to mu ọgbẹ ọkan ba iyawo rẹ?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ní ibẹrẹ ọdun yii ni Okposo salaye pe ni opin ọdun to kọja 2021, ni oun tẹkọ leti rinrin ajo lọ silẹ Amẹrika, ti oun si yan obinrin kan ni ọrẹ.

O ni lootọ ni oun mọ pe igbesẹ naa ko tọna, ti ko si ba ifẹ Ọlọrun mu gẹgẹ bi akọrin ẹmi ati pe oun ti se igbeyawo.

Koda, oju n ti oun, ti oun si kabamọ iwa pansaga ti oun hu yii ati irora nla ti igbesẹ naa ti mu ba iyawo oun, Ozioma, idile oun ati oun gan alara.

Ninu lẹta iforijin naa ni Sammie Okposo ti wa kede pe nibayi ti oun ti n wa ọna lati rin ni alaafia pẹlu Ọlọrun, oun si n tọrọ aforijin siwaju.

Okposo ni "Mo ti da ara mi duro na kuro ninu gbogbo awọn isẹ to jẹ mọ ti iransẹ Ọlọrun titi ti maa fi ni idapada tootọ.

Eyi ni igbesẹ to tọna niwaju Ọlọrun, mo si jẹ Ọlọrun ati awọn eeyan ni gbese yii."

Akọrin ẹmi naa wa sọ fun Ozioma aya rẹ pe oun kabamọ pupọ pe oun ko ojuti ba, ti oun si da igbagbọ ati igbẹkẹle to ni ninu oun.

"Idarijin rẹ se pataki fun mi lori iwa ijakulẹ ti mo hu, mo si gbadura pe titi gbogbo ọjọ aye mi ni maa fi maa wa ọna lati tun gbe igbagbọ ati igbẹkẹle naa ro."

Mo tọrọ aforijin lọwọ awọn ọmọ ijọ mi - Sammie Okposo

Sammie Okposo wa tun tọrọ aforijin ninu lẹta naa, lọwọ awọn baba ati iya rẹ ninu igbagbọ, to fi mọ awọn ojisẹ ihinrere fun iwa aimọra to hu naa.

O ni oun kabamọ pupọ nipa ihuwasi oun naa pẹlu afikun pe ti kii ba se igbagbọ wọn pe Ọlọrun lo pe oun si isẹ iransẹ, oun ko ba ti si mọ.

O tun wa rawọ ẹbẹ si awọn ọmọ ijọ rẹ atawọn eeyan to n tẹle oun lẹyin lai mọ oun ni ojukoroju pe oun n tọrọ aforijin pe oun ja wọn kulẹ.

Bakan naa lo ni oun kabamọ nipa irora ọkan ti oun ti le mu ba wọn amọ ki wọn tubọ maa gbadura fun oun ni.

Gbajúmọ̀ olórin ẹ̀mí Sammie Okposo jáde láyé!

Iroyin to n tẹ wa lọwọlọwọ yii sọ pe gbajugbaja olorin ẹmi, Sammie Okposo ti jade laye lonii ọjọ Kẹẹdọgbọn Oṣu Kọkanla.

Nigba ti ileeṣẹ iroyin BBC kan si manija Sammie, fi aridaju han pe lootọ ni o ti jade laye amọ ko fẹ kede orukọ ara rẹ.

Laipẹ yii ni orukọ Okposo gba ori ayelujara kan nigba to tu aṣiri ara rẹ sita gbangba to n tọrọ aforijin lọwọ iyawo rẹ, Ozioma fun aṣemaṣe to ṣe pẹlu obinrin mii lorilẹede Amẹrika.

Iroyin naa gba igboro kan titi ti ọpọlọpọ eeyan n ran ẹnu mọ ọ ti wọn si n sọ oniruuru ero wọn.

Iṣẹlẹ yii mu ko wọgile awọn eto kan to yẹ ko ti kọrin nibẹrẹ ọdun yii.

Sammie Okposo ṣi fi atẹjade kan sita loju opo rẹ lanaa to n dupẹ lọwọ awọn ti wọn jọ ṣe akanṣe eto orin iyin ni ipinlẹ Eko.

A o maa mu ẹkunrẹrẹ iroyin wa fun yin.