Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ tọkọ-taya àti ẹnìkan f̀́ẹsùn ìjínigbé àti ìpànìyàn nípìnlẹ̀ Ogun

Awón afurasi

Oríṣun àwòrán, Ogun Police

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti mu tọkọtaya kan, ati ẹlomii fun ẹsun pe wọn ṣekupa oniṣowo kan ti wọn ji gbe. Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Abimbola Oyeyemi sọ ninu atẹjade kan to fi sita pe, ọkọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2020 ni awọn afurasi naa, Adebayo Adewumi, iyawo rẹ, Okereke Funmilayo, ati Adebowale Sanni, gbe Otunba abayomi Ajayi Smith. O ni ni nkan bi aago meje aabọ owurọ ni wọn gbe ni agbegbe Igbeba, niluu Ijebu Ode. Gbogbo igbiyanju ileeṣẹ ọlọpaa lati doola ọkunrin naa lo ja si ofo, nitori pe awọn ajinigbe pa ọkunrin naa lẹyin ti wọn gba miliọnu mẹẹdogun Naira owo itusilẹ lọwọ ẹbi rẹ.

SP Oyeyemi sọ pe lati igba naa ni ọlọpaa ti n wadii awọn ọdaran naa. "Ninu ṣu Kẹsan-an, ọdun yii ni igbiyanju awọn ọlọpaa so eso rere, nigba ti aṣiri tu si wọn lọwọ pe awọn afurasi naa ti n gbeero lati ji iyawo oloogbe ati ọmọ rẹ kan gbe. O ni iwadii awọn ọlọpaa nilu Ijebu-Ode, lo yọri si bi wọn ṣe tọpinpin ẹnikan lara awọn afurasi naa, Adebowale Sanni, ẹni ọdun marundinlọgọta, de ilu Ikeji Arakeji, nipinlẹ Osun. Oun si lo jẹwọ fun awọn ọlọpaa pe oun ti n ṣọ obinrin naa, Olusola Roseline Ajayi, lati ji gbe. "O ni Adebayo Adewumi, to jẹ ọkọ afurasi kẹta, Olufunmilayo, lo ran oun." Funmilayo yii jẹ ọkan lara awọn oṣiṣẹ oloogbe Ajayi, oun si lo n tu aṣiri ọga rẹ fun wọn.

Bi aṣiri ṣe tu ree

Adebowale Sanni jẹwọ fun ọlọpaa pe Ọgbẹni Adewumi lo juwe ile itura to jẹ ti ẹni ti wọn fẹgbe, ati awọn ile itaja rẹ mii, fun oun. "Aṣẹ to pa fun mi ni pe a gbọdọ pa obinrin naa ati ọmọ rẹ, lẹyin ti a ba gba owo itusilẹ wọn tan gẹgẹ bi a ṣe ṣe fun ọjọ rẹ ni ọdun meji sẹyin. "Eyi jẹ ọna lati ma jẹ ki aṣiri tu." Bi Ọgbẹni Sanni ṣe jẹwọ, lo ran ọlọpaa lọwọ lati mu iyawo Adewumi, to jẹ oludari awọn ile itaja eroja ikọle oloogbe. Ọjọ kẹta ni ọwọ tẹ Adewumi funra rẹ. Agbẹnusọ ọlọpaa, SP Abimbola Oyeyemi sọ pe iṣẹ jibiti ni Adewumi kọkọ n ṣe, ko to o bẹrẹ ijinigbe. "O ma n fojusun awọn to ba jẹ olowo, ko to o ko awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ jade lati ji ẹni naa gbe. "Lati ẹnu iyawo rẹ, Funmilayo si lo ti gba awọn iroyin nipa Ọtunba Ajayi Smith, ti wọn pa." O ni iwadii fihan pe asunwọn meji ni asunwọn meji lo n lo ni banki lati fi awọn owo iṣẹ ibi to n ṣe pamọ si. Miliọnu mẹrinlelọgbọn ni wọn ba ninu asunwọn kan, ti ikeji si ni miliọnu kan aabọ Naira ninu. Bakan naa ni wọn gba ọkọ ayọkẹlẹ nla kan lọwọ rẹ. Kọmisanna ọlọpaa nipinlẹ Ogun, CP Lanre Bankole, ti wa paṣẹ pe ki wọn gbe awọn afurasi naa lọ si ile ẹjọ ni kete ti iwadii ba pari. Bakan naa lo gboriyin fun awọn ọlọpaa to ṣiṣẹ takuntakun ti ọwọ fi tẹ wọn