Àwọn ọmọ Nàìjíríà kò gbọdọ̀ gba PDP láyè láti ṣàkóso ọrọ̀ orílẹ̀ èdè yìí mọ́ - Tinubu

Oríṣun àwòrán, Others
Olùdíje sípò Ààrẹ Nàìjíríà lẹ́gbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, Asiwaju Bola Tinubu ti ní òun kò ní kó ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà kéré rárá bí wọ́n bá dìbò fún òun láti di ààrẹ Nàìjíríà.
Tinubu sọ èyí níbi ìfilọ́lẹ̀ ìpolongo ètò ìdìbò rẹ̀ ní pápá ìṣeré Teslim Balogun ní ìpínlẹ̀ Eko lọ́jọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kẹrìndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kọkànlá, ọdún 2022.
Ó ní òun yóò gbájúmọ́ ètò ẹ̀kọ́, ètò ìlera àti ìgbanisíṣẹ́ tí òun bá di ààrẹ tí àwọn ọmọ Nàìjíríà kò ní gbàgbé òun títí láé ní àwọn ẹ̀ka yìí.
Tinubu ní òun yóò ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn gómìnà tó ní èrò ìlọsíwájú fún Nàìjíríà láti ri wí pé àwọn èròńgbà yìí wá sí ìmúṣẹ.
Ẹ ò gbọ́dọ̀ ẹgbẹ́ PDP láyè láti dépò ìjọba mọ́
Nígbà tó ń tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Tinubu ní kò yẹ kí àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè yìí fún ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party láàyè mọ́ láti ṣàkóso ọrọ̀ Nàìjíríà mọ́ nítorí àkóbá tí wọ́n ti ṣe sẹ́yìn.
Tinubu fi kun pé ọṣẹ́ tí ẹgbẹ́ PDP ṣe sí ọrọ̀ Nàìjíríà ló ṣokùnfà gbogbo ìpèníjà tí Nàìjíríà ń bá fínra títí di àsìkò yìí.
Ó ní gbogbo ọdún mẹ́rìndínlógún tí wọ́n lò nípò, kàkà kí wọ́n ṣe àwọn àkànṣe iṣẹ́ tí yóò mú ìlọsíwájú bá orílẹ̀ èdè yìí, ní ṣe ni wọ́n ti ọrọ̀ ajé Nàìjíríà mẹ́rẹ̀.
Bákan náà ló rọ àwọn ènìyàn láti lọ gba káàdì ìdìbò wọn láti lè ri wí pé wọ́n kópa nínú ètò ìdìbò gbogbogboò lọ́dún 2023.
Lára àwọn tó kópa níbi ètò náà ni Abẹnugan ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin, Femi Gbajabiamila, Gómìnà ìpínlẹ̀ Plateau, Simon Lalong Bako, Gómìnà ìpínlẹ̀ Kano, Abdullahi Ganduje, Gómìnà Katsina, Aminu Bello Masari, Dapo Abiodun tí ìpínlẹ̀ Ogun, Gómìnà Gboyega Oyetola ti ìpínlẹ̀ Osun, àtàwọn mìíràn.
Atiku, ẹ̀ẹ̀méló lo fẹ́ máa jáde dupò, lọ jókòó jẹ́ẹ́ – Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Oludije sipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu APC, Bola Tinubu ti ṣe yẹyẹ oludije lẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar lori iye igba to ti dije du ipo aarẹ lorilẹede Naijiria.
Tinubu lọ sọ ọrọ yii lasiko to ṣe ipade pẹlu awọn ara agbegbe Niger Delta, ti Ọba Pere ti Gbaramatu, Oboro-Gbaraun II (Aketekpe, Agadagba) lori awọn ohun to fẹ fun awọn araalu.
Atiku to jẹ ẹni ọdun mẹrindinlọgọrin lo ti kuna ni ẹẹmarun un to ti dijẹ du ipo aarẹ ni ọdun 1992, 2007, 2011, 2015 ati 2019.
Lasiko ti Tinubu n ba awọn ara ilu Gbaramatu sọrọ lo ni gbogbo ohun ti wọn fẹ ti wọn ṣe alaini ni oun maa pese fun wọn.
‘’Orilẹede Naijiria ko nilọ awọn onirọ nipa statistic, ẹ dibo fun awọn to mọ ọna.’’

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Awọn ohun amayedẹrun ti ẹ fẹ to fi mọ afara, ileẹkọ giga fasiti ati gbagede iṣere ni agbegbe Ogidigben ni maa ṣe fun yin.
Tinubu ni awọn ohun to wa si ọkan oun leleyii, ti oun yoo si ṣe fun awọn eniyan.
‘’Orilẹede Naijiria ko nilọ awọn onirọ nipa statistic, ẹ dibo fun awọn to mọ ọna.’’
Kabiyesi bi mo ṣe duro si iwaju yin yii awọn to ku to n dije du ipo ko pọ rara. Ẹyọkan sọ wi pe oun ni Atiku, igba meloo lo fẹ dije du ipo ni Naijiria? Ẹ lọ sọ fun pe ko lọ joko, o to gẹ!
‘’Ẹnikeji pe ara rẹ ni statistics, ṣe statistic la fẹ jẹ ni, arithmetic ti awọn ara India ko ni idahun fun.’’
‘’Mi o kan tilẹ le darukọ rẹ nitori ko si nkankan to daju ninu gbogbo nkan to n sọ’’
‘’Naijiria ko nilo statistics, ẹni ti yoo ṣiṣẹ, ti ko ni pa irọ fun awọn araalu ni a fẹ!’’















