Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ lásìkò tí Peter Obi àti Charles Soludo pàdé lẹ́yìn gbas-gbos tó wáyé láàrín wọn

Oríṣun àwòrán, C C SOLUDO 2021 MOVEMENT
Lẹyin ohun to farajọ ede aiyede laarin gomina ipinlẹ Anambra tẹlẹ ati gomina to n ṣejọba lọwọ nibẹ, o jọ bii pe awọn mejeji ti pari ija to ṣeeṣe ko wa laarin wọn.
Aworan ibi ti Ọjọgbọn Charles Soludo ati Peter Obi ti di mọ ara wọn ti bẹrẹ si n fa ori ayelujara ya lẹyin ti Soludo sọ ninu atẹjade kan ṣaaju pe Peter Obi ko ni jawe olubori ninu eto idibo Aarẹ ọdun to n bọ.
Soludo ni bo tilẹ jẹ pe Peter Obi mọ pe oun ko ni bori ninu ibo naa, o n mọọmọ fi akoko awọn ololufẹ rẹ ṣofo ni bo ṣe n fun wọn ni ireti aṣeyọri.
Lẹyin atẹjade naa ni ọpọ araalu bẹrẹ si n fi erongba wọn lede, bi awọn kan ṣe n sọ pe ododo ọrọ ni Soludo sọ, lawọn ti Peter Obi n sọ pe ọrọ naa ko gba ẹnu Soludo rara.

Oríṣun àwòrán, C C SOLUDO 2021 MOVEMENT
Nibo ni Soludo ati Obi ti pade?
Ile ijọsin St. Patrick's Cathedral, to wa niluu Akwa ni wọn ti pade.
Eto ti isin idupẹ alufaa Most Rev. Paulinus Ezeokafor, to jẹ biṣọọbu ẹkun Awka si ni wọn lọ ṣe.
Lodi si erongba awọn ololufẹ awọn mejeji, ṣe ni wọn di mọ ara wọn bii pe ko si ede aiyede kankan laarin wọn ṣaaju.
Ki lo ṣẹlẹ laarin Soludo ati Obi gan?
Ṣaaju ni Soludo ti kọkọ sọ lori ẹrọ amohunmaworan kan pe bi igba ti eeyan ba fi owo ilu ṣofo lawọn eto kan ti Obi kowo ipinlẹ naa le lori lasiko rẹ gẹgẹ bii gomina.
Lẹyin naa lo kọ atẹjade kan to gun gbọrọ pe eremọde lasan ni Obi n ṣe lati du ipo Aarẹ Naijiria nitori ko le wọle, Obi funra rẹ si mọ pe oun ko le wọle.
O ni “Ka ma tan ara wa jẹ, Peter Obi mọ pe oun ko le wọle, ko si le wọle.”
Soludo sọ pe ayọ ni Obi n ta, ayo to si n ta naa ni ko jẹ ko pada sinu ẹgbẹ oṣelu APGA, ati pe aarin awọn oludije meji pere ni ibo naa wa, Obi ko si lẹnu nibẹ.
Obi fesi pada
Nigba to n sọrọ nibi apero kan nile ẹkọ eto okowo, Lagos Business School, Obi sọ pe oun ti ṣe iwọn ti oun le ṣe gẹgẹ bii gomina Anambra, akoko Soludo si ree lati ṣe ojuṣe tirẹ.
O ni “Ọjọgbọn ni Soludo, o si mọ iṣẹ idagbasoke daadaa.”
“Oniṣowo ni mi, mo ti ṣe iwọn ti mo le ṣe gẹgẹ bii oniṣowo, Ọjọgbọn ni Soludo, ki oun naa lọ ṣe iwọnba to le ṣe gẹgẹ bii Ọjọgbọn ti ori rẹ pe.”












