Naked: Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ èèyàn yọ̀nda ìhòhò ara wọn lọ́fẹ̀ẹ́ láti ya fọ́tò “Tunich artwork” létí òkun, ìdí rèé

Ihoho eniyan pupọ

Èèyàn tó to ẹgbẹrun meji abọ to wa ni ihoho ti dẹmọ lowurọ kutu hai ni eti okun Bondi Beach ni Sydney fun fọto iṣẹ iyaworan kan ti wọn ṣe lati ṣe itaniji lori arun jẹjẹrẹ agọ ara.

Ẹni to n ṣakoso yiya aworan naa ni ayaworan ilẹ Amẹrika kan, Spencer Tunick to n ṣe iṣẹ akanṣe kan eyi to da lori gbigba awọn ara Australia niyanju lati maa ṣe ayẹwo ara loorekoore.

Ofin yipada o si faye gba bibọ ara silẹ nihoho fun igba akọkọ leti okun. Australia jẹ orilẹede kan lagbaye to n koju iṣoro jẹjẹrẹ agọ ara. Eyi jẹ ohun ti ajọ agbaye to n ṣewadii nipa arun jẹjẹrẹ sọ.

Ihoho eniyan pupọ

Lati nnkan bii ago mẹta abọ owurọ lorilẹede wọn ni awọn to yọnda ara wọn ti korajọ si eti okun lati kopa ninu akanṣe eto yiya aworan naa.

Eyin ni wọn ṣe pẹlu ajọ́ṣepọ awọn aṣoju ayẹwo ara (Charity skin Check Champions) lasiko ayajọ ọsẹ ipolongo lodi si arun jẹjẹrẹ.

“A ni anfani lati ṣe ilanilọyẹ nipa ayẹwo ara, ori mi si wu...” lati wa sibi, ṣe iṣẹ ọna mi ati pe ki n yẹ awọn ara naa si ki n si daabo bo wọn,” gbajugbaja oniṣẹ ọna lagbaye, Tunick sọ bẹẹ gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin Reuters ṣe sọ ọ.

Ihoho eniyan

“Mo roo wipe eleyi jẹ ero to dara mo si nifẹ lati maa bọ aṣọ mi silẹ lẹba okun Bondi.”

Ilumọọka ni Tunick fun iṣẹ ọpọlọ nipa ihoho elero pupọ ni awọn ibudo agbaye to laami laaka.

Ihoho eniyan pupọ