Gbogbo àwọn ajìjàgbara tó ń bínú la óò bá sọ̀rọ̀ – Tinubu

Oríṣun àwòrán, others
Oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ni ijọba oun yoo wa gbogbo ọna lati rii pe oun pẹtu si ọkan awọn awọn adijagbara ti wọn binu lori idi kan tabi omiran lorilẹede Naijiria.
Tinubu sọ eleyi nigba to kopa ninu ipolongo ibo aarẹ to waye ni ile ijọba nipinlẹ Ebonyi, pẹlu oludije sipo Gomina ẹgbẹ naa nipinlẹ ọhun, Pa Ngele Orutu paapaa ni Abakaliki.
O rọ awọn alatilẹyin ẹgbẹ oṣelu APC pe ki wọn gba kaadi idibo wọn, eyi ti yoo fun wọn ni anfani lati dibo fun aṣeyori ẹgbẹ naa lọdun 2023.
Tinubu fẹkun pe ko si idi kankan fun ija ati jagidijagan laarin awọn ọmọ orilẹede Naijria lori ẹni ti yoo jẹ aarẹ, nitori oun yoo rii pe oni kalaku ko ni ẹtọ wọn, ti oun ba jẹ aarẹ lọdun to n bọ.
“Itẹsiwaju ni a fẹ, alaafia ni a fẹ, a ri pe a ba awọn to binu sọrọ. Ija ki n yanju nkan, ti a ba jọ joko ki a ṣorọ, a le yanju gbogbo ọrọ yii.
“Ti n ba di aarẹ a le sọrọ ninu oṣu karun un ọdun to n bọ.”
Odun mẹrindinlogun ti PDP fi ṣejọba lo jẹ aṣedanu - Tinubu
Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ṣapejuwe ọdun ti ẹgbẹ oṣelu PDP lori iṣejọba gẹgẹ bi aṣedanu nitori bi wọn ṣe kuna lati yanju awọn iṣoro ẹka ijọba, eyi ti ko fun wọn anfani lati pese ohun amayedẹrun fun awọn araalu
“APC nikan ni ẹgbẹ oṣelu to fẹ ilọposiwaju fun orilẹede yii, ko ki nṣe ẹgbẹ oṣelu PDP. A wa ti de si aarin yin bayii lati mu ilọsiwsiwaju de baa yin.
“Alaga ẹgbẹ oṣelu ati awọn iyoku ṣẹ iṣẹ gidi lati rii pe gomina Uman wa ni ara wọn lonii gẹgẹ bi ọkan lara wọn.
“ O ti han gbangba pe ko si mimi to le mi ẹgbẹ oṣelu APC bayi nitori pe gbogbo awọn jankajanka ti darapọ mọ ẹgbẹ wa.”















