Àwọn nǹkan tí a fi $1bìlíọ̀nù tí a rí gbà lọ́wọ́ àwọn jẹgúdújẹrá padà rè é - Ìjọba Nàìjíríà

Ààrẹ Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Twitter

Ijọba orilẹede Naijiria sọ pe biliọnu kan dola ni awọn owo ilu t’awọn kan ko pamọ eyi ti awọn ti gba pada lati igba ti aarẹ Muhammadu Buhari ti de ipo loṣu karun un ọdun 2015.

Minisita feto idajọ to tun jẹ agbẹjọro agba lorilẹede Naijiria, Abubakar Malami lo sọ bẹẹ lẹyin ipade igbimọ alaṣẹ ijọba Naijiria to waye l’Ọjọru.

O ni “ọkan lara opo ti iṣejọba Muhammadu Buhari duro le lori ni gbigbogun ti iwa ijẹkujẹ at’awọn nnkan miran.”

O ni idi niyi ti igbimọ naa ti fi fọwọ si iwe ilana antẹle kan lati tubọ ro igbesẹ igbogun ti iwa ijẹkujẹ lagbara sii.

Agbẹjọro agba orilẹede Naijiria naa ni ijọba sí n kọminu lori bi iwa afikun isuna se n figba gbogbo waye, ti wọn si ti n wa ọna lati doju kọọ

Minisita feto idajọ lorilẹede Naijiria, Amofinagba Malami tun salaye pe gbogbo owo ti ijọba gba lowo awọn to ja ilu lole lawọn ti da pada sinu eto ọrọ aje Naijiria.

Amofin Malami ni pataki julọ lara awọn ẹka ọrọ aje ti wọn da owo naa pada si ni ẹja ile iṣẹ lugbẹ, to si ti ni ipa to jọju lara mimu adinku ba eto ọrọ aje Naijiria.

O ni owo ti wọn gba pada lara eyi ti wọn ko pamọ si orilẹẹde Switzerland lọdun 2017 le ni ọọdunrun biliọnu naira, ijọba si ti gbin in pada sinu eto ileṣẹ ati oṣi wọgbẹ ni ibamu pẹlu ipinnu aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari.

“Lara owo yii lati na fun eto ironilagbara N- Power ati tradermoni at’awọn eto miran ti a gbe kalẹ.”

Ni osu kesan an ọdun 2022 ni Malami ti n sọ pe won tubọ n fi awọn owo naa sọlẹ sori ipese eto igbayegbadun kakkiri orilẹede Naijiria.

Lara awọn ohun amayedẹrun naa ni atunṣe awọn apa kan opopona marosẹ Eko si Ibadan ati opopona Abuja si Kano at’awọn akanṣe iṣẹ miran bẹẹ.