Ọkùnrin tó fipá bá ọmọdékùnrin ọmọ ọdún 5 lòpọ̀ dójú ikú kó sí gbaga ọlọ́pàá

Afurasi

Oríṣun àwòrán, Ogun Police

Ọwọ́ iléeṣẹ́ ọlọ̀pàá ìpínlẹ̀ Ogun ti tẹ arákùnrin kan, Sikiru Ajibola fẹ́sùn wí pé ó fipá bá ọmọdékùnrin kan ní àjọṣèpọ̀ tí ẹ̀mí ọmọ náà fi bọ̀.

ọmọ ọdún márùn-ún ni Ajibola fipá bálòpọ̀ ní agbègbè Ogijo, ìpínlẹ̀ Ogun.

Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ ọlọ́pàá Ogun, Abimbola Oyeyemi fi léde lọ́jọ́ Àbámẹ́ta ní alága àdúgbò Olorunwa Arogbeja Ogijo lo lọ fi ọ̀rọ̀ náà tó àwọn ọlọ́pàá létí.

Oyeyemi ní ará àdúgbò náà ló wá fi ẹjọ́ sun òun wí pé ará àdúgbò àwọn kan fipá bá ọmọkùnrin ọmọ ọdún márùn-ún ọ̀hún ló pọ̀ tí ọmọ náà sì dágbére fáyé nígbà tí afurasí náà ń ṣiṣẹ́ ibi náà lọ́wọ́.

Ó fi kun pé lọ́wọ́ kan ni àwọn ọlọ́pàá gba àdúgbò náà lọ tí wọ́n sì nawọ́ gán afurasí náà.

Ó tẹ̀síwájú pé afurasí náà ti jẹ́wọ́ wí pé ọkpunrin ni òun máa ń bá lòpọ̀ àti pé lásìkò tí òun ń bá ọmọ náà sùn lọ́wọ́ ló dágbére fáyé.

Àtẹ̀jáde náà tún fi kun pé afurasí náà jẹ́wọ́ wí pé inú igbó kan ní òun gbé kòtò sí tí òun sì sin ọmọ náà síbẹ̀.

Agbẹ́nusọ ọlọ́pàá ní afurasí náà ti mú àwọn ọlọ́pàá lọ sí ibi tó sin òkú ọmọ ọ̀hún sí.

Ó ní kọmíṣọ́nà ọlọ̀pàá Ogun, Lanra Bankole ti darí pé kí wọ́n gbé ẹjọ́ náà lọ sí ẹ̀ka tó ń ṣèwádìí ìwà ọ̀daràn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ fún ìwádìí tó péye.