Èyí lohun tílé ẹjọ ṣe lẹ́yìn tí Rahamon Adedoyin kùnà láti farahàn nílé ẹjọ́ lórí ikú Timothy Adegoke

Oríṣun àwòrán, Timothy Adegoke
Ileẹjọ giga nipinlẹ Osun tun tí sun Igbẹjọ lori iku akẹkọọ fasiti Obafemi Awolowo, Timothy Adegoke síwaju.
Onidajọ Adepele Ojo gbe igbesẹ naa lẹyin ti ẹlẹrii Afurasi akọkọ, Dokita Rahmon Adedoyin, ko fi arahan sì ileẹjọ loni.
Adajọ ni oun ko le kofiri sì awọn yooku lai ṣe pe oun gbọ ọrọ ẹnu ẹlẹrii to fẹ jẹri fun afurasi naa.
Adajo Adepele Ojo wa sun Igbẹjọ ọhun sì ọjọ kẹẹdọgun oṣu kejila odun ti wa yii.
Gbogbo awọn afurasi meje ọhun lo farahan sì ile ẹjọ loni.
Oti ti lọ ọdun kan bayi tí Igbẹjọ naa bẹrẹ











