Àlá àti ìlépa mi láti gba ife ẹ̀yẹ ‘World Cup’ ti dópin – Cristiano Ronaldo

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gbajumọ ẹlẹsẹ ayọ ọmọ orilẹede Portugal, Christiano Ronaldo ti sọ pe ala to ga julọ ti oun ni ni lati rii pe orilẹede Portugal pẹlu wa lara awọn orilẹede ti wọn n darukọ wọn pẹlu gbigba ife ẹyẹ agbaye. Cristiano Ronaldo sọ eyi ninu ọr to fi soju opo ayelujara rẹ gbogbo lọjọ Aiku lẹyin ti Portuga fidirẹmi kuro ni idije ife ẹyẹ agbaye Qatar 2022 lọjọ Satide. Igba akọkọ niyi ti Ronaldo yoo sọrọ lẹyin ijakulẹ ikọ Portugal lọwọ Morocco.
Ronaldo ni ala naa dopin lọjọ Satide amọ eyi ko yi ifọkansin oun fun orilẹede Portugal pada, biotilẹjẹ wi pe oniruru ọrọ alufansa leti oun ti gbọ. O ni lootọ oun ti gba oniruuru ami ẹyẹ kaakiri agbaye ati lorilẹede Portugal pẹlu ṣugbọn ko si eyi to le dabi ki Portugal gba ife ẹyẹ agbaye loju oun.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
“Mo ja fun un. Mo ja fun ala rere yii. Ni idije marun un, mo gba goolu wọle ni ide ife ẹyẹ agbaye laarin ọdun mẹrindinlogun ti mo fi wa pẹlu awọn odu agbabọọlu pẹlu atilẹyin ẹgbẹlẹgbẹ awọn ọmọ orilẹede Portugal. Mo fi gbogbo ẹmi mi silẹ fun un. Mi o fi igba kọọkan sinmi ala yii. “Amọṣa, fun ibanujẹ ọkan mi, ala yii dopin lana...”
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Morocco na Portugal pẹlu ami ayo kan si odo lọjọ Satide lati tẹ siwaju si ipele to kangun si aṣekagba. Igba akọkọ si niyi fun orilẹede kankan ni Afrika lati de ipele naa. Ko daju pe Ronaldo yoo le tun kopa mọ ni idije ife ẹyẹ agbaye pẹlu bi o ṣe jẹ wipe yoo ti le lẹni ọdun mọkanlelogoji nigba ti idije miran yoo ba fi waye lọdun 2026.








