Obasanjo kọrin re ki Adeleke, ó ní bó ṣe ń jó, ló ń ṣiṣẹ́ gidi lÓsun

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Ààrẹ tẹ́lẹ̀ nílẹ̀ Nàìjíríà, Oloye Olusegun Obasanjo ti ṣe káre sí gómìnà ìpínlẹ̀ Osun, Ademola Adeleke.
Obasanjo ní bí Adeleke ṣe ń jó fún Ọlọ́run, náà ló ń gbé àkànṣe isẹ ṣe ní ìpínlẹ̀ Osun.
Obasanjo gbosuba bẹẹ fún Adeleke níbi ìsìn ìkórè kẹrindínlógún ìjọ Love of Christ ti Wòlíì Esther Ajayi tó wà lágbègbè Victoria Island nilu Eko.
Lásìkò to ń sọ̀rọ̀ níbi ìsìn náà, Obasanjo yọ suti ètè sáwọn èèyàn tó ń fapa janu nípa bí Adeleke ṣe máa ń jó ijo ajokara.
Obasanjo wá yonbo Adeleke lórí bo ṣe ń jó náà, ó ní Ọlọ́run ló ń jó fún.

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Obasanjo pé gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe fi tó òun létí, ijo jíjó yìí kò dá àṣeyọrí Adeleke dúró torí ó ń ṣiṣẹ́ takuntakun bíi gómìnà ni ìpínlẹ̀ Osun.
Adeleke náà sì dìde lásìkò tí Obasanjo ń sọ̀rọ̀ yìí láti ṣe apọnle ààrẹ àná náà.
"Jíjó ijo fún Ọlọ́run jẹ ohun ìwúrí, pẹ̀lú pé ó tún fi iṣẹ rere kun.
Ìròyìn to ń kàn mí láti Osun jẹ àwọn ìròyìn ìdàgbàsókè tó ń wáyé nibẹ.
Ọlọ́run tó ń jo fún náà yóò da ìbùkún rẹ̀ lé ọ lórí àti ìjọba rẹ.
Bákan náà ni mo tún gbọ́ pé o jẹ gómìnà tó máa ń tẹti sí aráàlú, wọn ní o máa ń gba ìmọ̀ràn tọmọdé-tagba.
Inú mi dùn láti gbọ nípa èyí, mo sì ń ké sí Ooni ilé Ife àtàwọn oríadé miran nipinlẹ Osun láti ṣe àtìlẹyìn fún gómìnà Ademola Adeleke.
Èyí ni yóò jẹ ki ìṣẹ́ rere tó ń ṣe túbọ̀ tẹsiwaju.
Mo sì ń rọ gómìnà Adeleke náà láti ṣíṣẹ papọ pẹ̀lú àwọn ọba alaye, àwọn àgbààgbà àtàwọn èèyàn ti ọ̀rọ̀ ìpínlẹ̀ Osun jẹ lógún."

Oríṣun àwòrán, Screenshot
"Majẹmu tí mo bá Ọlọ́run dá ní pe máa padà wa dúpẹ́"
Nígbà tó ń fèsì sí ọ̀rọ̀ Obasanjo, gomina Adeleke ni òun maa n jo láti mọ rírí Ọlọ́run tó dá ayé àti ọ̀run, ojú kìí si ti oun láti jo fún.
" Ọ̀pọ̀ àwọn wolii lọkunrin lobinrin lo sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé máa di gomina l'Osun, èyí tó ti wá sí ìmúṣẹ báyìí.
Majẹmu tí mo bá Ọlọ́run dá ní pe máa padà wa dúpẹ́, kí n sì yín lógo gẹ́gẹ́ bí mo ti n ṣe ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé ìjọsìn."
Adeleke wá mẹnuba ọpọ àṣeyọrí rẹ láti ìgbà tó ti gorí àga gomina nipinlẹ náà.















