Nínú ìrìnàjò mi ni mo rí pé èèyàn gidi pọ̀ nínú ìran Hausa- Hafsoh Babatunde

Yoruba bọ, wọn ni ibi lile laa ti ba ọmọ ọkunrin.
Ọrọ yi ṣe rẹgi pẹlu ẹni taa mu wa ninu fidio wa tonii amọ ṣugbọn kan wa ninu rẹ.
Ẹni taa ba nibi lile yi kii ṣe okunrin.Orukọ arabinrin yi to dantọ nidi alupupu gigun a si maa jẹ Hafsoh Olayemi Babatunde.
Ki lo sun de idi gigun alulupupu taa mọ si Power Bike ati pe iru iriri wo lo ti ri lẹnu igba to pinnu pe oun yoo maa gun alupupu kaakiri orileede Naijiira?
Ki a kọkọ mu alaye diẹ wa nipa iru ẹni ti Hafsoh jẹ.
Hafsoh, ọmọ ẹgba, ẹni ọdun mokandinlọgbọn yii jẹ oṣiṣẹ aṣọbode ti a si tun maa ṣiṣẹ aransọ.
Amọ ohun to sọ pe o wu oun julọ ninu awọn nkan ti eeyan a maa ṣe ni gigun alupupu Power Bike.
Hafsoh sọ pe ọdun 2022 loun bẹrẹ si ni wa alupupu Power Bike.
Bẹẹ lo si ṣalaye pe oun ti wa alupupu kaakiri Naijiria.
O ni ni awọn ipinlẹ ariwa, mọkandilogun ni ibi toun ti wa alupupu de.
Ko tan sibẹ,Hafsoh ni ifẹ toun ni si alupupu wiwa yi ti gbe oun de Cameroon, Togo,Cotonou ati awọn ibo miranl.
Lori awọn ipenija to n koju nidi alupupu wiwa yi, Hafsoh ni oun koju ipenija lawọn orileede ilẹ okere nigba toun wa alupupu lọ sibẹ.
Ni tawọn ipinlẹ Naijiria, o sọ pe oun koju ipenija nigba toun lọ si awọn ipinlẹ bi Adamawa,Taraba,Nassarawa ati Gombe.
Amọ o fikun alaye rẹ pe boun ṣe koju ipenija, bẹẹ naa loun ni anfaani lati ni imọ si nipa aṣa ati iṣe awọn ẹya Hausa.
Gẹgẹ bo ṣe sọ fun BBC: ''gigun alulupupu ni ilẹ Ariwa jẹ ki n mọ pe eeyan gidi pọ ninu iran Hausa.''
















