ASUU fariga pé àwọn kò faramọ ìpinnu ìjọba àpapọ̀ láti jẹ kí ilé ẹ̀kọ́ fasiti dá ẹrú ará wọn gbé

Aworan ipade awọn alaṣẹ ẹgbẹ olukọ fasiti

Oríṣun àwòrán, ASUU

Ẹgbẹ olukọ fasiti Naijiria ASUU ti s pe awọn ko ni faramọ igbesẹ ijọba apapọ lati faaye agba awọn fasiti pe ki wọn maa da ọrọ ara wọn yanju.

Lọsẹ yi ni Minisita feto ẹkọ Ọjọgbọn Tahir Mamman sọ pe ijọba ti n ṣeto awọn ilana kan eyi ti yoo mu ki awọn fasiti maa da bukata ara wọn gbọ lai ṣe pe awọn da si ọrọ wọn.

Ẹgbẹ awọn olukọ fasiti sọ pe iru erongba ijọba yi ko ni so eso rere ati pe ijọba ko ro tawọn ọmọ Naijiria pẹlu igbesẹ yi.

Ninu ọrọ to ba BBC sọ olori ẹka ẹgbẹ olukọ fasiti ni Kano,Ọjọgbọn Abdulkadir Muhammad sọ pe erongba awọn ati ti ijọba ko papọ pẹlu nkan ti wọn n gbero lati ṣe yi.

O fikun pe igbesẹ ti ijọba apapọ fẹ gbe yi fihan pe wọn fẹ yẹra fun awn ojuṣe to gbe le ara rẹ lọrun tori pe oun lo loun ni fasiti apapọ pe ko si ẹni to ba oun ni.

Igbesẹ yi ko ni nkankan ṣe pẹlu eto ẹkọ Naijiria

Aworan awọn olukọ fasiti Ibadan lasiko iwọde ifẹhonuhan kan

Nigba taa beere lọwọ rẹ pe ṣebi ASUU ti n kọrin pe awọn fẹ ki ijọba yọwọ kuro ninu eto ẹkọ fasiti tipẹ, ki wa lo de ti wọn n tako igbesẹ yi, olukọ naa sọ pe iru eto tawọn n ja fun kọ leyi ti ijba n gbero.

O ni ''ominira taa n beere kọ ni iru eleyi tawọn ijọba n sọrọ rẹ''

O ni apẹrẹ nkan tawọn n beerẹ ni pe ki ijọba ma toju bọ bawọn ṣe n yan awọn adari ẹgbẹ naa ati ṣiṣe agbekalẹ awọn ofin ti ko ni mu idagbasoke ba fasiti Naijiria.

Bẹẹ lo mu apẹrẹ mii wa nipa bi ijọba yoo ṣe mu awọn ofin ti yoo lolati fi mu nira ba awọn olukọ fasiti.

Ninu rẹ lo sọ pe ti ilana owo oṣu sisan IPPIS wa to si ni ile ẹjọ ti dajọ pe ko bojumu pe ki wọn lo ilana yi lati fi san owo oṣu awọn olukọ fasiti.

O ni ''nigba tọrọ di ki wọn maa fi owo sidi iṣeto fasiti ijọba lawọn fẹ yọwọ,ta wa ni yoo pese owo fawọn fasiti ti ijọba sọ pe awọn lawọn ni wọn?''

O ṣalaye pe ''ti wọn ba ti n gbero pe fasiti ni yoo maa da bukata ara wọn gbọ,ki wọn yaa tete sọ fawọn obi to ni ọmọ nile ẹkọ pe ki wọn maa gbaradi lati san owo gọbọi niyẹn''

Awọn akẹkọọ ni yoo faragba ọrọ yi

Olukọ fasiti yi mẹnu ba bi alekun owo ẹkọ lawọn fasiti ti ṣe di ohun tawọn araalu n kọminu si.

O ṣalaye pe ''laipẹ yi lawọn fasiti kan gbe owo ile ẹkọ lọ soke lati nkan bi ẹgbẹrun lọna ogoji Naira si ẹgbẹrun lọna aadọjọ si ẹgbẹrun lọna igba Naira lai ṣe pe wọn ti yọwọ kuro ninu iranwọ fawọn fasiti''

O ni ohun ti igbesẹ yi yoo tunmọ si ni pe awọn alaṣẹ fasiti ni yoomaa wa owo fi kọ awọn ile ikawe, aaye iwadii bẹẹ si ni wọn yoo ma san owo oṣu oṣiṣẹ́ ati awọn nkan mi ti fasiti yoonilo.

O sọ pe''ṣe lọdọ awọn ọmọ talaka la tifẹ gba gbogbo owo yi?''

Ọjọgbọn Abdulkadir Muhammad sọ pe awọn ko faramọ igbesẹ ti ijọba n gbero yi tori pe ko le muanfaani ba awọn ati ẹka eto ẹkọ fasiti Naijiria.

Lakotan o ni ilana tawọn n beere fun ni eleyi ti yoo faaye gba awọn lati se idari ẹgbẹ awọn lai ṣẹ pe ijọba toju bọ yiyan awọn ti yoo dari eto fasiti.