Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ UNILAG fẹ̀hónúhàn, ọ̀rọ̀ bẹ́yìn yọ pẹ̀lú ọlọ́pàá

Awọn ọlọpaa fu taju-taju tu awọn akẹkọọ fasiti UNILAG ka to n ṣe ifẹhonuhan lori afikun owo ileewe wọn ka, koda meji ninu wọn lo tun ko si gbaga
ọlọpaa.
Femi Adeyeye ati Philip Olatinwo lorukọ awọn akẹkọọ meji ọhun tawọn agbofinro ju sinu ọkọ ti wọn gbe wa.
Adeleye sọ ninu atẹjiṣẹ to fi ṣọwọ si ile iṣẹ Punch pe lati oniruuru agọ ọlọpaa lawọn agbofinro ti wa sibi tawọn ti n ṣe ifẹhonuhan.
Olufẹhonuhan miiran, Bayo to bawọn akọroyin sọrọ ṣalaye pe niṣe lawọn ọlọpaa yin taju-taju si aarin awọn akẹkọọ to n fẹhonum han lati tu wọn ka.

Ọrọ bẹyin yọ nibi ifẹhonuhan ọhun lẹyin ti awọn ọlọpaa da taju-taju bolẹ nibẹ.
Bayo ni ọpọ akẹkọọ lo fẹsẹ fẹ, koda oun gan an ni lati wa ibi sa pamọ si ni.
Fidio kan tawọn ti wọn ka silẹ ṣe afihan bi awọn akẹkọọ kan ṣe gbe iwe ilewọ soke bi wọn ṣe n sare kiti kiti nigba tawọn ọlọpaa yin taju-taju.
Ẹwẹ, oludipo sipo aarẹ fẹgbẹ oṣelu African Action Congress (AAC), Omoyele Sowore ti kesi ileeṣẹ ọlọpaa lati fi awọn akẹkọọ ti wọn mu silẹ.
Ṣaaju lọjọ Iṣẹgun ni ẹgbẹ awọn akẹkọọ ni Naijiria, NANS ti sọ fawọn ọlọpaa awọn akẹkọọ UNILAG yoo fi ẹhonu han wọọrọwọ l’Ọjọru.
Bakan naa ni ajọ NANS kilọ fun ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS pe ki wọn ma ṣe idena fawọn akẹkọọ nibi ifẹhonuhan wọn nitori ẹtọ wọn ni.
Ṣugbọn ọrọ bẹyin yọ nibi ifẹhonuhan ọhun lẹyin ti awọn ọlọpaa da taju-taju bolẹ nibẹ.

















