Akeredolu gba iṣẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn agbẹnusọ igbákejì rẹ̀

Akeredolu/Aiyedatiwa

Oríṣun àwòrán, Akeredolu/Aiyedatiwa

Gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu ti gba iṣẹ lọwọ awọn agbẹnusọ igbakeji rẹ, Lucky Aiyedatiwa.

Agbẹnusọ Akeredolu, Richard Olatunde lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjade kan.

Atẹjade naa ni “Ijọba ti jawe ẹ lọ gbele yin fun gbogbo awọn agbẹnusọ ti wọn yan fun gomina ipinlẹ Ondo, Arakunrin Oluwarotimi Akeredolu Aketi, SAN, CON, amọ ti ofin gba laaye lati maa ṣiṣẹ fun igbakeji gomina.”

“Awọn agbẹnusọ ti ọrọ na kan ni akọwe gomina Kenneth Odusola; oluranlọwọ pataki si gomina lori eto iroyin, Oladipupo Okunniga; ati oluranlọwọ pataki si gomina fun aworan yiya, Samson Abayomi Adefolalu.

“Gbogbo wọn gbọdọ jọwọ awọn dukia ijọba to wa lọwọ wọn fun adele akọwe agba ọọfisi igbakeji gomina.”

Yatọ si awọn oluranlọwọ pataki yii, Akeredolu tun tu ikọ akọroyin to n ba igbakeji ọhun ṣiṣẹ.

O tun dari awọn akọroyin to n tẹle igakeji gomina naa kiri ki wọn pada sawọn ileeṣẹ iroyin ti wọn n ba ṣiṣẹ tabi si ọọfisi wọn tẹlẹ.

Akeredolu ti wa paṣẹ pe ileeṣẹ to n risi eto iroyin ipinlẹ Ondo nikan ni ko maa jabọ gbogbo iroyin nipa igbakeji rẹ ọhun.

Titi di asiko yii, ko si ẹni to tii le sọ eredi igbesẹ tuntun naa.

Amọ ṣa, lati nnkann bii oṣu mẹta ṣeyin ti Akeredolu dubulẹ aisan ni igbakeji rẹ, Lucky Aiyedatiwa ti n dele de e, to si n ṣoju rẹ ni gbogbo awọn akanṣe ipade to yẹ ko lọ.

Ṣaaju iroyin idaduro awọn alabaṣiṣẹ igbakeji gomina yii ni iroyin kan ti kọkọ gbode pe Aiyedatiwa ko ṣe olootọ si Akeredolu.

Amọ Aiyedatiwa ni ti Akeredolu ni oun n ṣe, oun ko si le fi ọbẹ ẹyin jẹ gomina naa niṣu bo tilẹ jẹ pe awọn madaru kan n tiraka lati da aarin oun ati ọga rẹ naa ru.