Ohùn tó yẹ kò mọ nípa IPhone 15 tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde àti ìyè tó jẹ́

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ileeṣẹ Apple ti fidi rẹ mulẹ pe ẹrọ ibaraẹnisọrọ IPhone 15 tuntun yoo ni aye ati gba ina sara ni kiakia.
Apple ni IPhone tuntun yii ti wọn se ifilọlẹ rẹ lọjọ isẹgun yoo ni aye igbana sara 'type C' eyi to jẹ itẹwọgba ni gbogbo agbaye.
Bakan naa ni wọn tun ṣe ifilọlẹ ago Apple pẹlu ọpọlọpọ anfani to lekun si.
Ṣugbọn sọrọ sọrọ kan ni bi Apple ṣe kuna lati se atunse si ohun ti wọn n pe ni 'headline grabbing' lọdun yii yoo dun ọpọlọpọ.
Awọn ohun tuntun to wa ni foonu naa ni
- IPhone 15 ni ọpọlọpọ atunse, ina tó wa lara foonu naa jade daada, bakan naa ni ẹrọ ayaworan ti dara si.
- IPhone 15 jẹ ẹgbọn tí aburo, IPhone 15 pro àti Pro max.
- Bakan naa ni ti ago, ayipada naa de ba oun.
Ṣugbọn ọpọlọpọ awuyewuye lo tí bẹrẹ lori pe njẹ awọn eeyan yo ra foonu pẹlu bí o ṣe jẹ lowo gbọgọ ati pe ko fi bẹ yatọ si ti awọn ti atẹyin wa lọ.
Elo ni ẹrọ ibaraẹnisọrọ yii?
Ni ilẹ UK, IPhone 15 yoo bẹrẹ pẹlu iye owo £799, ti awọn to jẹ pro yoo si jẹ £999.
"Lati jẹ ki awọn eeyan ra foonu yii yoo nira pupọ pẹlu bi ipo ti ọrọ aje wa ni asiko yii," Paolo Pescatore salaye.
Ipin idokowo Apple ti bẹrẹ si ni walẹ lọjọ Isẹgun ti ileeṣẹ naa si kuna lati se ohun to yẹ lẹyin ti ìjọba orilẹede China palasẹ fun awọn osisẹ ìjọba lati ma lo foonu naa mọ.












