Wo Jamila àti Ayodele tí Tinubu yàn sípò mínísítà ọ̀rọ̀ ọ̀dọ́

Oríṣun àwòrán, Lauretta Onochie/X
Aarẹ Bola Tinubu ti yan ọdọ meji Jamila Bio Ibrahim ati Ayodele Olawande gẹgẹ bi minisita ọrọ awọn ọdun ati igbakeji rẹ.
Iyansipo yii waye lẹyin ti aarẹ yọ Ọgbẹni Abubakar Momoh, ẹni ọgọta ọdun to kọkọ yan sipo naa.
Gẹgẹ bi oludamọran aarẹ Tinubu lori ọrọ iroyin, Ajuri Ngelale ṣe sọ, aarẹ Naijiria ti fi orukọ awọn mejeeji ṣọwọ sile igbimọ aṣofin l’Abuja lati fontẹ lu wọn.
Ta ni Jamila Bio Ibrahim ati Ayodele Olawande ti Tinubu yan sipo minisita?
Ta ni Jamila Bio Ibrahim ati Ayodele Olawande ti Tinubu yan sipo minisita?
Gẹgẹ bi akọsilẹ to wa loju opo ayelujara rẹ, Dokita Ibrahim jẹ oloṣelu ni Naijiria.
Bakan naa lo jẹ aarẹ ẹgbẹ awọn ọdọbinrin lorilẹede Naijiria.
Dokita Ibrahim tun jẹ alagbawi idagbasoke awujọ.
Oun gan an oludamọran agba tẹlẹ ri lori ọrọ idagbasoke fun gomina ipinlẹ Kwara.
O si tun jẹ alẹnulọrọ fun ajọ to n ri si idagbasoke ilẹ Afirika, AUDA-NEPAD.
Ọgbẹni Ayodele Olawande ni tiẹ jẹ onimọ nipa idagbasoke awujọ.
Ṣaaju iyansipo rẹ yii, Olawande olori awọn ọdun ni Naijiria ninu ẹgbẹ oṣelu APC.
Ọgbẹni Olawande tun ṣiṣẹ ni ọfiisi oludamọran pataki si aarẹ lori ọrọ ọgbọn inu lati ọdun 2019 si 2023.
Ẹwẹ, aarẹ Tinubu rọ awọn mejeeji lati ṣiṣẹ takun takun gẹgẹ bi ọdọ ni ipo ti oun yan wọn si.
Bakan naa ni aarẹ tun sọ fun wọn pe ki wọn lo ọgbọn inu ti Eleduwa fun wọn gẹgẹ bi ọdọ lati ṣiṣẹ.















