Tinubu tún mórílé Amẹrika lẹ́yìn tó dé láti India ati UAE

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu/Facebook
Aarẹ Bola Tinubu yoo tun gbera lọ si orilẹede Amẹrika lọjọ Aiku ọjọ kẹtadinlogun oṣu kẹsan an yii.
Ipade gbogbogbo awọn olori orilẹede ajọ iṣọkan agbaye, UNGA ni aarẹ Tububu n lọ ṣe niluu New York.
Ajuri Ngelale to jẹ oludamọran pataki lori ọrọ iroyin si aarẹ lo fidi ọrọ yii mulẹ ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Abamẹta.
Eyi igba akọkọ ti Tinubu yoo lọ fun ipade awọn olori orilẹede ajọ UN lati igba to ti di aarẹ Naijiria.
Ngelale ṣalaye ninu atẹjade naa pe akori ipade naa ni ‘’titun igbẹkẹle ninu ifọwọsowọpọ ṣe lagbaaye.’’
Ngelale ni ọjọ kinni ipade yii gan an ni aarẹ Tinubu yoo sọrọ nibi ipade ọhun niluu New York.
O ni Tinubu yoo sọọ lori iyipada oju ọjọ, idagbasoke, ifọwọsowọpọ lagbaaye ati ọna lati wa ojutuu si oniruuru ipenija to n koju ọmọniyan lagbaaye.
Bakan naa ni Ngelale sọ pe Tinubu yoo ṣe ipade pẹlu oniruuru awọn olori orilẹede lagbaaye to fi mọ awọn aarẹ ajọ EU, ọrilẹede Brazil ati ti South Africa.
Tinubu yoo tu ṣe ipade pọ pẹlu awọn olori ileeṣẹ nla nla bii Microsoft, Meta Technologies, Exxon Mobil ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Awọn gomina, minisita atawọn alabaṣiṣẹpọ aarẹ ni yoo kọwọọ rinrin ajo pẹlu rẹ lọ si Amẹrika.















