O lé ní ẹgbẹ̀rún kan ìgbéyàwó tó forí ṣánpọ́n ní Kano, kí l'ohun tó wà nídìí ọ̀rọ̀ yìí?

Aworan obinrin to n sunkun

Ọpọ eeyan lo ti n kọminu nipinlẹ Kano lẹyin ti ajọ ajafẹtọmọniyan kan gbe iroyin jade to fihan pe iye igbeyawo to fori ṣọnpọn n lọ soke si ni ipinlẹ naa.

Ninu abajade iwadii ti wọn kede saraye gbọ,wọn ni laarin oṣu meloo kan o to nkan bi igbeyawo ẹgbẹrun to tuka to si ti to ilọpo iye rẹ ni dede asiko kanna lọdun to kọja.

“Awọn ọdọ lo pọ ninu awọn ti igbeyawo wọn fori sọnpọn ti pupọ ninu wọn si bi ọmọ kan,meji mẹta tabi mẹrin.''

Ajọ yi tun sọ pe o ṣsṣe ki iye awọn ti igbeyawo wọn tuka tawọn ṣe akojọ rẹ ju bẹẹ lọ nitori awọn eleyi ti wọn mu de eti igbọ wọn ni wọn kọ kalẹ.

Wọn sọ pe orukọ tawọn ko jọ wa lati ijọba ibilẹ mẹrinlelogoji to wa ni Kano ati nibi awọn igbẹjọ igbeyawo to tuka tawọn ko jọ lati ile ẹjọ.

Apapọ iye iṣẹlẹ igbeyawo to tuka ti wọn lawọn ko jọ lati ibẹrẹ ọdun fihan pe o to

1080 ti eyi si jẹ ilọpo meji iye iṣẹlẹ ọdun to kọja.

Ọrọ yi jẹ nkan tawọn eeyan n jẹ lẹnu ni Kano to si mu ki ọpọ sọ pe asiko to bayii ki awọn alaṣẹ gbajumọ eto idanilẹkọ ti ọrọ baa le ni iyanju.

Comrade Hafiz Sanusi Sanka to jẹ ọkan ninu awọn ọmọ ajọ yi sọ pe ọrọ igbeyawo to n tuka ni Kano yi nilo akiyesi ati iwoye pataki.

Ki lo fa ti ọpọ igbeyawo fi n fori ṣanpọn

Lọdun to kọja ituka igbeyawo 288 ni wọn ni akọsilẹ fun.

Amọ lọdun yi o ti lọ soke debi pe wọn ri akọsilẹ igbeyawo to le ni ẹgbẹrun kan.

Iye yi to ilọpo mẹrin ti ọdun 2022 gẹgẹ bi ajọ naa ṣe sọ.

Ajọ naa sọ pe iwadii awọn lori ọrọ yi fihan pe lara awọn nkan to n fa ki igbeyawo maa tuka ni awọn nkan wọnyi wa:

  • Iṣẹ
  • Ai si idanilẹkọ to peye ṣaaju igbeyawo
  • Ai si eto ṣiṣe to gunrege
  • Mọlẹbi to n da si igbeyawo lọna ti ko bojumu

Lara awọn olugbe ipinlẹ Kano to ba BBC sọrọ ni wọn sọ pe aini suuru naa wa lara awọn okunfa ti igbeyawo fi n fori ṣanpọn.

Ọkan ninu wọn sọ fun wa pe ''ni nkan bi ọdun mẹẹdogun sẹyin, ọrọ ituka igbeyawo yi ko buru to yi idi si ni pe ti ko ba si suuru,igbeyawo ko le duro''

Arabinrin kan sọ ni tiẹ pe aisi idanilẹkọ naa fawọn tọkọtaya ṣaaju igbeyawo jẹ okunfa igbeyawo to n tuka.

''Awọn obinrin kan kii ṣe onimọtoto tawọn mii a si maa keti ikun si aṣẹ ọkọ wọn.Fawọn ọkunrin o ni aisi ikapa lati ṣe ojuṣe wọn wa lara okunfa igbeyawo to n tuka''

Ṣugbọn ninu gbogbo idi tawọn eeyan ṣalaye, eleyi to jọ pe ẹnu ko lori rẹ ni pe awujọ gaan fun ararẹ ti bajẹ debi pe o n da kun iye igbeyawo to n tuka ni gbogbo igba.

Eyi lawọn kan sọ pe o yẹ ki ijọba mojuto dipo ṣiṣe eto igbeyawo fawọn eeyan nibi ayẹyẹ nla.

Wọn a maa ya owo tabua sọtọ fun eto yi koda ti tọdun yi, wọn ti ṣe gbogbo eto kalẹ de igbeyawo elero pupọ.

O le ni ẹgẹrun kan tọkọtaya ti ijọba Kano fẹ so pọ ni igbeyawo nibi ayẹyẹ nla kan ti wọn yoo si fi nkan elo ile ati owo diẹ ṣe iranwọ fun wọn.

Aworan awọn ti ijọba Kano ko jọ lati ṣe igbeyawo