Àwọn afọbajẹ nílùú Oyo gbé Seyi Makinde lọ sílé ẹjọ́ lórí ìyànsípò Aláàfin, olórí Oyomesi ní òun kò mọ ohunkóhun nípa rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Facebook/OyoAlaafin/Seyi Makinde
Iroyin kanti gba ori ayelujara pe awọn afọbajẹ niluu Oyo ti pe Gomina Makinde lẹjọ lori itẹ Alaafin to ṣofo.
Iroyin naa ni awọn Oloye marun un ni wọn tọwọ bọ iwe ẹjọ naa.
Awọn oloye ti orukọ wọn han ninu iwe ipẹjọ naa ni Basorun Ilu Oyo, Yusuf Ayoola, Lagunna, Wakee; Oyedepo, Akinniku Oyo, Amusa Yusuf, Areago Basorun, Wahab Oyetunji ati Alapo Oyo, Gbasebo Mufutau.
Bakan naa ni awọn olupẹjọ fi orukọ Adajọ agba ati orukọ kọmisana fun ijọba ibilẹ ati oye jije mọ ara orukọ awọn ti wọn pe lẹjọ.
Iwe ẹjọ naa, ti nọmba idanimọ rẹ jẹ HOY/38/2023, lo ti wa ni iwaju ileẹjọ giga ipinlẹ Oyo bayii.
Ẹbẹ awọn afọbajẹ naa ni pe ki ile ẹjọ fofin de Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ati awọn ẹmẹwa rẹ lati mase le daburu eto yiyan ẹni ti yoo jẹ alaafin tuntun.
Bakan ni wọn fẹ fi ofin de Gomina lati mase le e ni anfani lati yọ awọn afọbajẹ naa gẹgẹ bii Oloye ilu Oyo tabi tu apapọ Oyomesi ka.
Bakan naa ni wọn ko fẹ ko yan awọn oloye mii lati bẹrẹ iyansipo Alaafin tuntun.
"Emi ni Basorun, tii se olori afọbajẹ nilu Oyo amọ n ko mọ ohunkohun nipa ẹjọ ti wọn pe gomina"
Ọna lati fidi iroyin yii mulẹ lo mu ki BBC Yoruba kan si olori Oyomesi tii se asaaju igbimọ afọbajẹ nilu Oyo, to tun jẹ Basorun ilu naa, Oloye Wahab Ayoola.
Lasiko ọrọ rẹ pẹlu BBC Yoruba, Basorun fọhun sita lori iroyin to ni awọn afọbajẹ Oyo gbe Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde lọ ile ẹjọ fun ẹsun pe ko jẹ ki awọn yan Alaafin tuntun.
Oloye Ayoola wa fidi rẹ mulẹ pe Oyomesi kọ lo gbe Gomina naa lọ ileẹjọ ati pe oun ko mọ nkankan nipa ọrọ to jẹ mọ ileẹjọ.
O ni oun ko ri idi kan pataki ti awọn afọbajẹ yoo fi ni awọn fẹ gbe Makinde lọ si ileẹjọ nitori ko ṣe nnkan fun awọn.
"Gẹgẹ bi Basorun, Oyo Mesi kọ lo pe Gomina lẹjọ"
Oloye Ayoola tẹsiwaju pe “Oyo o pe Gomina Makinde lẹjọ, ki ni Gomina ṣe fun wa ti a fi pe lẹjọ?
“N ko mọ nnkan nipa ọrọ yii, ti ẹ ba fẹ wadi, ẹ lo wadi lọdọ awọn ti wọn ni awọn pe ẹjọ.
“Gẹgẹ bi Basorun, Oyo Mesi kọ lo pe Gomina lẹjọ.”















