Àkókò ti tó láti gbé ìjọba fún Kamala Haris – Biden sọ fún Amẹrika

Joe Biden

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Aarẹ Amẹrika, Joe Biden, ti sọ fun awọn eeyan ilẹ naa pe akoko ti to lati gbe ijọba fun iran tuntun.

Biden lo sọ ọrọ naa lasiko to n ṣalaye eredi ti ko fi du ipo Aarẹ fun saa keji.

Biden, to jẹ ẹni ọdun mọkanlelọgọrin sọ pe oun kede pe oun ko ṣe mọ, ti oun si ṣatilẹyin fun Kamala Harris lọna ati mu irẹpọ ba ẹgbẹ oṣelu Democrat nilẹ naa.

Ikede Biden yii nipa Kamala n tumọ si pe Kamala ti lanfani lati dije gẹgẹ bii ẹni ti yoo ṣoju ẹgbẹ wọn ninu ibo Aarẹ bo tilẹ jẹ pe awọn mii naa nifẹ si ati dije.

Ninu ọrọ to ba awọn ọmọ Amẹrika sọ lori ẹrọ amohunmaworan ni Biden ti sọrọ fun iṣeju mọkanla.

Biden ni “mo bu ọwọ fun ọọfisi yii, ṣugbọn mo fẹran orilẹede mi ju ọọfisi naa lọ.

“Mo ti pinnu pe ọna to dara ju fun ilọsiwaju ni ki n gbe ijọba fun iran tuntun, ọna to dara ju niyi lati mu irẹpọ waye lorilẹede wa.”

Biden sọ siwaju si pe oun yo pari saa oun ki oun to fi ipo Aarẹ silẹ.

Lẹyin naa lo juwe Kamala gẹgẹ bii obinrin to ni “iriri, alakinkanju ati alabaṣiṣẹpọ to ṣe e gbọkan le.”

Aarẹ naa sọ pe oun gbagbọ pe iṣe ti oun ti ṣe nipo Aarẹ ka oun yẹ lati du ipo fun saa keji amọ ko yẹ ki ohun ti oun n fẹ bori itẹsiwaju orilẹede oun.

O ni “ohun rere kan nipa ilẹ Amẹrika ni pe kii ṣe awọn ọba alade ati apaṣẹ waa lo n ṣejọba, awọn araalu lo n ṣejọba, ọwọ ẹyin araalu ni ijọba Amẹrika wa.”

Ṣugbọn ko mẹnuba bi awọn olori ẹgbẹ Democrat kan ṣe n gbogun tii lati ma dije fun saa keji ninu ọrọ rẹ.

Kamala Harris jẹ asinwin alakatakiti ti yoo ba orilẹede wa jẹ, ti wọn ba fun ni aaye lati gba akoso orilẹede naa - Trump

Wayi o, oludije ninu ẹgbẹ oṣelu Republican, Donald Trump ti juwe Kamala Harris ti Biden n ṣatilẹyin fun gẹgẹ bii ẹni to n siwin.

Trump, tii se ẹni ọdun mejidinlọgọrin, kede loju opo ayelujara rẹ, Truth Social, ni alẹ Ọjọru pe pe ‘wọn ko fi bẹẹ ni oye ohun ti aarẹ n sọ, o buru pupọ.’

Saaju nigba to n sọrọ nibi iwọde to waye ni ilu Challotte nipinlẹ North Carolina, oludije fun ipo aarẹ fẹgbẹ oselu Republican naa wa kọlu aarẹ Biden ati igbakeji rẹ, Kamala Harris.

Trump wa se apejuwe Biden bii aarẹ to tii ba orilẹede Amẹrika jẹ julọ ninu itan ilẹ naa.

"Fun ọdun mẹta ati aabọ, Kamala Harris to jẹ opurọ lo jẹ idid lẹyin ọgba to n ti ọpọ asise Biden lẹyin.

O jẹ asinwin alakatakiti ti yoo ba orilẹede wa jẹ ti wọn ba fun ni aaye lati gba akoso orilẹede naa."