Mourinho fẹ́ kojú Wenger nínú ìdíje miràn yàtọ̀ sí EPL

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Akọ́nimọ̀ọ́gbá ikọ̀ Manchester United Jose Mourinho ǹ gbèrò láti bá alátakò rẹ̀ Arsene Wenger pàdé lọ́jọ́ iwájú.
Wenger tó ti jẹ́ akọ́nimọ̀ọ́gbá fún ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lu Arsenal fún bí ọdún méjìlélógún ló fìdí rẹmi pẹ̀lú ikọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ayò méjì s'ódo ní Old Trafford lọ́jọ́ àìkú.
Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà ló jẹ́ àgbákẹ́yìn fún Wenger nílé Man U k'ótó fipò rẹ̀ sílẹ̀ ní Arsenal lópin sáà yìí.
Wọ́n se ìmọyì fún Wenger kí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà tó bẹ̀rẹ̀.
Àgbàọ̀jẹ̀ akọ́nimọ̀ọ́gbá Man U tẹ́lẹ́ rí Alex Ferguson l'ógbé ife fàdákà náà fún Wenger láti mọ'yì rẹ̀.
Mourinho wòye pé òun àti Wenger sì lè pàdé nńú ìdíje mìíràn yàtọ̀ sí Premier League nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.








