Barcelona fàgbà han Deportivo láti gba ife ẹ̀yẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ikò Barcelona gba ife ẹ̀yẹ La liga lẹ́yìn tí wọ́n f'àgbà han ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lu Deportivo La Coruna pẹ̀lú àmìn ayò mẹ́rin sí méjì
.Àgbàọ̀jẹ̀ agbábọ́ọ̀lu n nì Lionel Messi ló gbá àmìn ayò mẹ́ta wọle, tí ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lu náà fi jáwé olúborí nínú ìdíje náà.
Èyí ni ìgbà karùndínlọ́gbọ̀n tí ikò Barcelona yóò gba ife ẹ̀ye La liga.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lu alátakò Real Madrid ní wọ́n ti gba àmin ẹ̀yẹ náà lẹ́ẹ̀mẹtàlélọ́gbọ̀n.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ìgbà kẹrìndínlọ́gbọ̀n nìyí tí Messi yóò gbá àmìn ayò mẹ́ta wọle nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ kan ṣoṣo fún ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lu tí o'ń sojú àti orílẹ́-èdè rẹ̀.








