Iniesta yóò kúró ní Barcelona

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àgbàọ̀jẹ̀ agbábọ́ọ̀lù ikọ̀ Barcelona, Andres Iniesta, ti kéde wí pé òun yóò fi ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù náà sílẹ̀ l'ópin sáà yìí
Iniesta yóò kúrò ní Barcelona lẹ̀yìn ìgbà t'óti gbábọ́ọ̀lù fún ikọ̀ náà fún ọdún méjìlélógún.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Agbábọ́ọ̀lù náà t'ójẹ́ ọmọ bíbí orílẹ́-èdè Spain ti ṣojú Barcelona nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ t'ódín díẹ̀ ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin láàrin sáà mẹ́rìndínlógún.
Iniesta gba ife-eyẹ mọ́kànlélọ́gbọ̀n pẹ̀lú ikọ̀ Barcelona.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Agbábọ́ọ̀lù náà sọ pé òun yóò kéde ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù tuntun tí òun yóò darapọ̀ mọ́ n'íparí sáà yìí.
Ìròyìn kan ni pé ó ṣeéṣe kí Iniesta darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Chongqing Dangdai Lifan ní ìdíje líìgì orílẹ́-èdè China








