Mohamed Salah ti fẹẹ da bii Lionel Messi - Olukọni Liverpool

Oríṣun àwòrán, Reuters/Getty Images
Olukọni ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool, Jurgen Klopp, sọ wi pe Mohamed Salah "ti fẹẹ" di ẹni ti wọn yoo ma darukọ nigba kan naa pẹlu Lionel Messi lẹyin igba to jẹ Watford ni bọọlu mẹrin l'ọjọ Abamẹta (Saturday).
Salah ni agbabọọlu to gba bọọlu sawọn ju ninu awọn idije liigi to lagbara ju ni Yuroopu lasiko yii - oti kọja Messi Barcelona ati atamatase Tottenham, Harry Kane.
Sugbọn Klopp wi pe nnkan to jẹ ẹni ọdun mẹẹdọgbọn ilẹ Ijibiti ọhun logun ni ko kojumọ ere bọọlu rẹ.
O sọ wipe : "Ẹmi ko lero wi pe Mo n fẹ ki wọn fi oun we Lionel Messi."
"Messi ti n ṣe nnkan to n ṣe yii ni asiko to jọ ogun ọdun.

Oríṣun àwòrán, Reuters
"Agbabọọlu ti mo le ranti ti ere rẹ maa n lapa lara ikọ ere bọọlu bii Messi ni Diego Maradona.
Laarin osu mẹsan, Salah ti jẹ bọọlu mẹrindinlogoji (36) fun Liverpool - eleyi ko si agbabọọlu toi jẹ iru rẹ ri ni saa akọkọ l'Anfield - o si ni bọọlu mejidinlọgbọ (28) to jẹ ninu idije liigi ilẹ Gẹẹsi to ku ayo meje ti yoo fi pari.
Balogun ẹgbẹ agbabọọlu ile Gẹẹsi tẹlẹ ri, Steven Gerrard nigbagbọ wipe: "a sẹsẹ bẹrẹ sii ri nnkan nla ni".
Sugbọn isọwọ jẹ bọọlu Salah ti bẹrẹ sii jọ ti ogbontagi agbabọọlu Argentina, Messi.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Sugbọn Salah f'itẹriba si aseyọri rẹ, o si dupẹ lọwọ awọn ojugba rẹ fun bi wọn ko se gba ki ikọ Javi Gracia jẹ wọn ni bọọlu kankan.
Ọna to soro lati gba
Gẹgẹ bi ẹni ọdun marudinlọgbọn (25), Salah ni lati tẹpa mọ ise ko to da bii Messi lagbo ere bọọlu.
O gba ifẹsẹwọnọsẹ mẹta ninu idije liigi ilẹ Gẹẹsi nigba ti ẹgbẹ agbabọọlu rẹ tẹlẹ ri Chelsea fi gbe ife ẹyẹ liigi naa lọdun 2015, o si wa lara ikọ to ba Basel gba ife ẹyẹ meji laaarin ọdun 2012 ati 2014.
Agbabọọlu naa ti ran ilẹ Ijibiti lọwọ lati r'aye wọ idije ife ẹyẹ agbaye nigba akọkọ lẹyin nkan to le ni ọdun mẹẹdọgbọn.
Sugbọn Messi - ti awọn kan sọ wi pe on gba bọọlu fun ikọ Barcelona to lagbara ju lọ ninu itan - ti gba ife ẹyẹ liigi mẹfa, ife ẹyẹ Champions League mẹta ati ami ẹyẹ wura nibi idije Olimpiki nigba to wa l'ẹni ọdun mẹẹdọgbọn (25).
O si ti gba ami ẹyẹ agbabọọlu to mọ bọọlu gba julọ ti Ballon d'Or l'ẹmaarun.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Salah - ẹni to se n t'ẹnikan ko se ri
- Salah ti jẹ bọọlu mẹrindinlogoji (36) fun Liverpool ninu gbogbo idije - eleyi ti ko si agbabọọlu to jẹ iru rẹ ri fun ikọ Reds.
- O ti jẹ bọọlu to mejidinlogun ninu idije liigi ilẹ Gẹẹsi ni saa yii- agbabọọlu Afrika kan lo jẹ ju iye bọọlu naa lọ ninu saa kan (Bọọlu mọkandinlọgbọn (29) ti Didier Drogba jẹ ni saa 2009-10).
- Salah ni agbabọọlu ilẹ Ijibiti akọkọ to jẹ bọọlu mẹta ninu ifẹsẹwọnsẹ kan ninu idije liigi ilẹ Gẹẹsi, nigba ti ilẹ Ijibiti jẹ orilẹede kẹtalelogoji ninu awọn orilẹede to ni iru agbabọọlu to jẹ bọọlu mẹta ninu ifẹwọnsẹ liigi ilẹ Gẹẹsi kan. to si jẹ orilẹede Afrika kẹwa to ni iru agba bọọlu to se bẹẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images












